Premier League: Ta ni yóò gba Premier League láàrin Man City àti Liverpool?

Jurgen Klopp ati Pep Guardiola Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Premier League n yeruku lala

Oni lonii jẹ ẹni a bẹ lọwẹ! Loni ọjọ kejila, oṣu karun un ni idije Premier League yoo wa s'ipari ti a o si mọ ikọ agbabọọlu ti yoo gba ife ẹyẹ naa laarin Manchester City ati Liverpool.

Liverpool fẹ gbiyanju lati di ikọ agbabọọlu keji ninu itan ti yoo gba ife ẹyẹ Premier League mọ ikọ to n siwaju lọwọ lọjọ ti idije naa pari.

Liverpool to n tele Manchester City pẹlu ami ayo kan yoo gbalejo Wolves ni papa iṣẹre Anfield nigba ti Man City yoo waako pẹlu Brighton ni deedee aago mẹta ọsan ọjọ Aiku.

Man City ti gbayo mọkanlelaadọrun un sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtadinlogoji ti wọn ti gba ni saa yii nigba ti Liverpool gba goolu mejidindinlaadọrun sawọn.

Bakan naa, awọn mejeeji sun mọ ara wọn pẹkipẹki lori tabili Premier League lẹyin tu Man City n fi ami ayo marun le laadọrun siwaju ti Liverpool si wa ni ipo keji pẹlu ami ayo mẹrinlelaadọrun.

Image copyright BBC Sport
Àkọlé àwòrán Idije Premier League n yeruku lala

Igba kẹjọ re e ti idije ti ikọ to gba Premier League yoo foju han lọjọ ti idije naa pari.

Liverpool to ti pegede fun aṣekagba idije UEFA Champions League ko tii ri ife ẹyẹ Premier League fun ọgun mọkakandinlọgbọn bayii.

Ẹwẹ, akọnimọọgba Man City, Pep Guardiola ti sọ pe gbagbagba bii ike lawọn alatilẹyin City yoo ṣe gbaruku ti wọn nigba ti wọn ba koju Brighton.

Bakan naa, ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool sọrọ loju opo Twitter pe, ikọ naa ti gbiyanju ni saa ohun kohun to wu ko ṣẹlẹ lonii

Man City yoo di ikọ agbabọọlu akọkọ ti yoo gba ife ẹyẹ Premier League lera wọn laarin ọdun mẹwaa sẹyin ti wọn ba gba ife naa mọ Liverpool lọwọ lonii.