O burú jai! Cardiff fọ́wọ́ òsí júwe Europa fún Manchester United

Awon agba bọlu Manchester United Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Europa League ní Manchester United o pada fàbọ̀ sí oo

Kíní káti gbọ́ pé Cadiff ló fẹ̀yìn Manchester United gbolẹ̀ nínú ìdíje Premier League, ẹni ti a rò pé kò le pàgọ́ tó ń kóle alárinrin lọ̀rọ̀ náà jẹ.

Nathaniel Mendez- Laing ọmọ agbabọ́ọ̀lù Cadiff ló jẹ àmìn ayò méèjèjìí bótilẹ̀ jẹ pé Cadiff ń ṣe ó digbà ó ṣe fún ìdíje Premier League sùgbọ́n wọn ṣe àmi sílẹ̀ kí wọ́n to lọ, bi wọn se fẹnu Manchester United gbòlẹ̀.

Bí Mendez-Liang ṣe side gbígbá bọ̀lù sáwọn fún Cadiff lásìkò to gbá wòmí-ń-gbáa sí ọ̀ ti Diogo Dalot mú balẹ̀, sùgbọ́n ó si tún jẹ lẹ́yìn ti wọn wọlẹ́ sáà kejì.

Aṣọle wọn Neil Etheridge fí han pe bi àwọn tilẹ̀ bá wọn lalejo ó kù nibọ̀n ń ró lọ̀rọ̀ àwọn ló ba n mú gbogbo ìgbìyànju Manchester United láti gba góòlù sáwọn di pàbó.

Ìfìdírẹmi Manchester United túmọ si pé wọn United yege nínu ìfẹsẹwọnsẹ kan péré nínú méje to kangun si àṣekágbá ni sáà yìí