Premier League Top Scorer: Aubameyang, Mane àti Salah gba Golden boot

Agba bọọlu meta Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Pierre-Emerick Aubameyang(Arsenal), Agbabọọlu ọmọ Senegal Sadio Mane(Liverpool) àti Mohmmed Salah (Liverpool)

Ọmọ ilẹ̀ Afíríkà mẹ́ta ló gbà àmi ẹyẹ Golden boot ninu idije Premier League to kásẹ̀ nílẹ̀ lónìí,.

Àmí ẹ̀yẹ yìí túmọ̀ si pé àwọn mẹ́tà yìí ló gbá bọọlù sáwọn jùlọ nínú ìdíje Premier League.

Góòlù méjilélogun Sadio Mane ọmọ bibi orilẹ̀-èdè Senegal, Mohammed Salah ọmọ bibi Egypt àti ọmọ orílẹ̀-èdè Gabon Pierre-Emerick Aubameyang ni wọn fi pegede.

Sadio Mane Senagal àti Mohammed Salah Liverpool

Salah ti gba ami ẹyẹ Golden Boot ri tẹ́lẹ̀ ko to tún gbàá ni sáà yìí pẹlu bó ṣe gbá bọ́ọ̀lù sáwọn nínú gbogbo ìdíje to ti kópa nínú ìdíje ti Liverpool ti kópa ni sáà yìí.

Mane náà tí o ń gba fun Liverpool pẹ̀lú Salah kópa nínú ìfẹsẹwọnsẹ mẹ́rìndílógóji to si gbá bọ́ọ̀lù méjìlélógun tó fi mọ ti aṣekágbá pẹ̀lú Wolves lọ́jọ́ ti Premier League pari.

Bótilẹ jẹ́ pé àwọn méjèjì gbá góòlù mẹ́rinlélógóji sáwọn fún iikọ agbábọọlu Liverpool, kò mu wọn jáwé olúbori ninu àṣekágbá Premier League bí Manchester City ṣe gba ife ẹyẹ naa.

Àwọn méèjèjì ṣì ṣe pinu lati gbá bọ́ọ̀lù sáwọn tí wọn ba pàdé Tottenham Hotspur ninu aṣekagba Champions League ti yoo waye ní ọjọ kini osù kẹ́fà.

Gabon Pierre-Emerick Aubameyang ti Arsenal

Ni ti Aubameyang, àmì ẹyẹ Golden Boot tó gbà yóò dúró gẹ́gẹ́ bi gbà mábinu bi ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ ṣe fidirẹmi ti wọn ko le wọn ikọ̀ agbábọ̀ọ́lù mẹ́rin akọ́kọ́ ti wọn ó fi ni ànfani lati kópa ninu Champions League ni sáà tó ń bọ.

Sáà keji rèé re ti Aubameyang ti darapọ mọ Gunners.

Nínú ìfẹsẹwọnsẹ mẹ́rìdínlógóji to ti kópa, Aubameyang náà ti gbá bọ́ọ̀lù méjìlélógún sáwọn