Orílẹ̀ède Ghana fí Asamoah Gyan jẹ Balogun káàfàtà ikọ Black Stars

Aworan Asamoah Gyan ati Ayew Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Balogun meji ni ikọ Black Stars ni bayi

Balogun meji ni yoo dari ikọ agbagbọọlu Ghana,Black Stars lọ si idije Afcon 2019 ti yoo waye ni Egypt.

Andre Ayew ni Balogun ikọ naa ti Asamoah Gyan yoo ṣi jẹ Balogun kaafata fun ikọ Black Stars.

Wọn fun Gyan ni oye tuntun yi lẹyin ti wọn gba ipo Balogun lọwọ rẹ ti wọn si gbe fun Ayew.

Akọnimọọgba ikọ Black Stars,Kwasi Appiah ni awọn fi Gyan jẹ Balogun kaafata tori pe oun ni o dagba ju lọ laarin ikọ naa.

Igbesẹ Appiah yii ko sẹyin ipade ti ajọ to n mojuto ọrọ bọọlu ni Ghana ṣe lati mu ki ohun gbogbo pada sipo.

Lọjọ Aje ni Gyan kede pe oun ṣetan lati fẹyinti nidi ere boolu lati fẹhonu han lori bi wọn ṣe gba ipo Balogun ikọ lọwọ rẹ.

Ọpẹlọpẹ Aarẹ Ghana Nana Akufo-Addo to da si ọrọ naa lo mu ki Gyan yi ipinnu rẹ pada.

Saaju ki wọn to gba ipo yi lọwọ Gyan, oun ni Balogun ikọ Black Stars fọdun meje, ti o si jẹ́ goolu mẹtadinlọgọta fun ikọ Black Stars.

Ọrọ ẹni ti yoo jẹ Balogun ikọ Ghana jẹ eleyi ti o ti n mu wahala wa tipẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdun meje ni Gyan ti fi jẹ Balogun ikọ Black Stars

Ghana yoo gba ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ ninu idije Afcon pẹlu Benin lọjọ kẹẹdọgbọn, Osu Kẹfa.

Ọdun 1982 ni Ghana gba ife naa kẹyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulfatah Ahmed: Àwọn Kwara fẹ́ dán ilé ọkọ kejì wo ni lásìkò yí
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFootballers: ìkà láwọn aṣojú agbábọ̀ọ̀lù míì lágbàyé