Flying Eagles fàtòrì já ewé bọ̀wọ̀ fágbà 4-0 fún ikọ̀ Qatar

Aworan Aliu Salawudeen Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Flying Eagles fàtòrì já ewé bọ̀wọ̀ fágbà 4-0 fún ikọ̀ Qatar

Ikọ Flying Eagles orile-ede Naijiria ti jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ ninu idije fawọn ojẹwẹwẹ tọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ.

Idije naa to n lọ lọwọ ni orile-ede Poland jẹ ọkan ti ireti wa wi pe ikọ Naijiria yoo ti se daada.

Flying Eagles Naijiria jẹ goolu meji ni abala ikini ifẹsẹwọnsẹ naa lati ọwọ Maxwell Effiom to jẹ goolu akọkọ ni iṣẹju kejila.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFootballers: ìkà láwọn aṣojú agbábọ̀ọ̀lù míì lágbàyé

Offia sọ di meji ni iṣẹju kẹtalelogun, ti Tomiwa Dele Bashiru to n gba fawọn ọjẹ wẹwẹ Manchester City ati Aliu Salawudeen si de lade pẹlu goolu Kẹta ati ikẹrin ni abala keji.

Naijiria lo n lewaju isọri wọn pẹlu ami ayo mẹta bayii.

Ukraine ati USA lawọn orile-ede meji to ku ni isọri kẹrin, Group D.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulfatah Ahmed: Àwọn Kwara fẹ́ dán ilé ọkọ kejì wo ni lásìkò yí