FIFA Women World Cup 2019: Orúkọ agbábọ́ọ̀lù Super Falcons 23 tí yóò lọ sí France ti ṣarajọ

Diẹ lara awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons Image copyright Nff
Àkọlé àwòrán Super Falcons yoo si koju Norway, Korea ati France ni ipele akọkọ.

Asisat Oshola, Desire Oparanozie ati Onome Ebi jẹ pataki lara ikọ ẹlẹnimẹtalelogun ti yoo ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu obinrin ti Naijiria, Super Falcons ni France.

Idije naa ni yoo jẹ ti aṣekagba idije ife agbaye awọn obinrin l'orilẹ-ede France.

Oludari eto ibanisọrọ nileeṣẹ ajọ to n mojuto ere idaraya ni Naijiria, NFF, Ademọla Ọlajire ninu ikede kan to fi sita l'alẹ ọjọ Ẹti sọ pe orilẹ-ede Austria nibi ti Super Falcons wa lọwọlọwọ fun igbaradi ni olórí akọnimọọgba wọn, Thomas Dennerby ti kede orukọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAsisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Awọn mi i ti orukọ wọn tun wa ninu ikọ naa ni Tochukwu Oluehi, Chiamaka Nnadozie, Alaba Jonathan, Osinachi Ohale, Faith Michael, Chidinma Okeke, Rita Chikwelu, Ngozi Okobi-Okeoghene, Halimatu Ayinde, Ogonna Chukwudi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFootballers: ìkà láwọn aṣojú agbábọ̀ọ̀lù míì lágbàyé

Bakan naa ni Evelyn Nwabuoku, Amarachi Okoronkwo, Uchenna Kanu, Fransisca Ordega, Uchenna Chinaza, Anam Imo, Rasheedat Ajibade ati Chiwendu Ihezuo yoo kopa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999

Ọjọ Kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2019 ni Super Falcons yoo gbera kuro ni Austia lọ si orilẹ-ede France ti idije naa yoo ti waye.

Wọn yoo si koju Norway, Korea ati France ni ipele akọkọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIkọ̀ Super Falcons ṣetán láti kojú Equatorial Guinea