IAAF'S $130,000: Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn lórí ayélujára f'èébú ṣe Sunday fún Dalung

Solomon Dalung Image copyright Facebook/Solomon Dalung
Àkọlé àwòrán Owo ajọ IAAF

Ayelujara n gbona girigiri lori ọrọ ti minisita ọrọ ọdọ ati ere idaraya, Solomon Dalung.

Eyi ko ṣẹyin ọrọ to sọ pe ajọ to n ri si ere-eje lagbaye (IAAF) fẹ ba orilẹ-ede Naijiria lorukọ jẹ lori ọrọ $130,000 ti wọn ni ki Naijiria da pada.

Ajọ IAAF sọ pe awọn san aadoje ẹgbẹrun owo dọla ($130,000) le nigba ti awọn fowo iranwọ ranṣẹ si ajọ to n ri si ọrọ ere-ije ni Naijiria (AFN) lọdun 2017.

Ko da ajọ IAAF tun sọ pe awọn yoo f'ofin de Naijiria bi o ba kọ lati dawo naa pada lai pẹ.

Ṣugbọn minisita tutọ soke o si foju gba a, lẹyin to sọ pe Naijiria ko lẹbi rara ninu ọrọ to wa nilẹ yii.

Dalung ni oun ko le sọ pato boya ajọ IAAF ṣi owo san ni tootọọ tabi Naijiria tilẹ ṣe aṣiṣe kankan lori owo naa.

Minisita ni kilode ti ajọ IAAF ko ṣe mọ lẹsẹkẹsẹ pe awọn ti ṣi owo san fun Naijiria ti o fi wa jẹ pe lẹyin oṣu meji ni wọn ṣẹṣẹ mọ.

Dalung fikun ọrọ rẹ pe owo yii wa fun agbekalẹ ere ije kan ni, eleyi ti o si ti waye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde

Ṣugbọn ọgọọrọ eeayan lori ayelujara ni ko kọrin 're ki minisita lori ọrọ yii, @biolakazeem sọrọ loju opo Twitter rẹ pe oun fẹ ki ajọ IAAF f'ofin de Naijiria.

O ni oun fẹ wo bi minisita Dalung tabi minisita tuntun ti aarẹ Muhammadu Buhari fẹ yan yoo ṣe ti ọrọ ba gbẹyin yọ.

@Ezbaronkings sọrọ loju opo Twitter rẹ wi pe ki wọn bu ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika FBI gbọ ki wọn le f'ofin de minisita lati lọ si orilẹede Amẹrika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka

@LekeOluseyi tiẹ sọ pe otitọ to wa nibi ọrọ yii ni pe minisita ti na owo ọhun ni. O ni ko ju bayẹn lọ.

@Chima_Saboyo ni tirẹ woye pe Naijiria ti fi ori inu ba tode jẹ lori ọrọ owo yii. O ni Naijria ti ba anfaani lati tun ọrukọ orilẹede yii ṣe nipa ere idaraya jẹ.

O tun di ẹbi naa ru Aarẹ Muhammadu Buhari to yan Solomon Dalung sipo minisita.

@ververngida ni ohun ti Dalung n gbiyanju lati sọ fun ajọ IAAF ni pe ọlọlẹ to ba bi ti wọ inu ẹkọ ko le jade mọ.

O ni Dalung n gbiyanju lati sọ fun ajọ IAAF pe a kii da owo pada lorilẹede Naijiria

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àsìkò Amojúẹ̀rọ Seyi ni ló fi wọlé l'Oyo, kìí ṣe àsìkò èmi Omobolanle'

@Sekoni12322 sọ ni tirẹ pe oun n duro de ohun ti ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu yoo yoo ṣe lori ọrọ yii.

Ajọ IAAF si n reti ki Naijiria da owo wọn pada ko maa baa di wi pe wọn yoo f'ofin de wọn lati kopa ninu ere eje kaakiri agbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionToma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ