Port Harcourt: Afurasi tó fa ìpayà nílé ìwé ti bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá

Ile iwe
Àkọlé àwòrán,

Fidio to jade safihan awọn akẹẹkọ girama ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn lẹyin ti ọkan ninu won da ipaya sile.

Ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers ti fi panpẹ ọba mu ọmọ ile iwe girama ni ilu Port Harcourt to fi tajutaju si ara awọn ọmọ kilasi rẹ.

Opin ọsẹ ni fidio kan jade nibiti awọn ọmọ ile iwe girama ti n sa asala fun ẹmi wọn lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ ni ile iwe naa.

Ọlọpaa ninu atẹjade ti wọn fi lede sọ wi pe awọn ọmọ kilasi SS2 ati SS3 ti wọn ni ija ti tẹlẹ ni wọn fẹ sọsẹ fun ara wọn. Ọkan ninu wọn lo mu tajutaju wa lati ile, amọ ti ẹlomiran si mu u nibi to fi pamọ si to si fi si ara awọn ọmọ kilasii rẹ.

Awọn wọn yii lo bẹ jade gba oju ferese ti wọn si bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn, eleyii to da ipaya si lẹ, ti gbogbo ile iwe fi daru lọjọ naa.

Ile isẹ ọlọpaa naa wa fi da awọn eniyan loju pe ọrọ naa ki i se igbesunmọni tabi ikọlu, sugbọn aigboraẹniye laaarin awọn akẹẹkọ lo fa wahala.

Iwadii si n lo lori awọn to da wahala naa silẹ ni ile ẹkọ girama naa, ati wi pe Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹtadinlọgbọn ni ọkunrin to fi tajutaju naa yoo pada si agọ ọlọpaa.

Àkọlé fídíò,

Mike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil