FIFA U-20 World Cup: Amẹrika dá sẹ̀ríà fún Nàìjíríà nínú ààwẹ̀

Awọn agbabọọlu Flying Eagles Image copyright FIFA
Àkọlé àwòrán Ikọ Flying Eagles fidi rẹmi

Abuku oloronbo ni ẹgbẹ agbabọọlu Amẹrika fi kan ikọ agbabọọlu Naijiria, Flying Eagles ninu idije ife ẹyẹ agbaye FIFA U-20 lorilẹede Poland.

Ami ayo meji sodo ni ikọ Amẹrika fi fagba han Naijiria, ọdọmọde ẹleṣẹ ayo ti orukọ n jẹ Sebastian Soto lo gbayo mejeeji wọ le fun ilẹ Amẹrika.

Esi ifẹwọnsẹ naa jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu lẹyin ti Naijiria lu Qatar ni aludaku pẹlu ami ayo mẹrin sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn kọkọ gba ninu idije ọhun.

Ọjọbọ ni Naijiria yoo koju Ukraine ninu ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin ni abala akọkọ ninu idije FIFA U-20 to n lọ lọwọ lorilẹede Poland.

Ikọ agbabọọlu Naijiria nilo lati jawe olubori nigba ti wọn ba koju Ukraine lati le tẹsiwaju si ipele komẹsẹọyọ.

Image copyright FIFA
Àkọlé àwòrán Ikọ Flying Eagles fidi rẹmi

Gbagbagba ni ẹgbẹ agbabọọlu Amẹrika ati Naijiria n tele ara wọn ni isọri kẹrin ti wọn wa pẹlu ami ayo mẹta mẹta, bo tilẹ jẹ pe Naijiria lo wa ni ipo keji.

Ukriane lo wa loke tente pẹlu ami ayo mẹfa lẹyin ti wọn jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn gba pẹlu Amẹrika ati Qatar.

Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu ni Naijiria sọrọ loju opo Twitter rẹ pe ikọ Flying Eagles yoo gbiyanju lati fiya jẹ Ukraine ninu ifẹsẹwọnsẹ Ọjọbọ.

Naijiria ko tii gba ife ẹyẹ agbaye FIFA U-20 ri, koda orilẹede Ghana nikan ni orilẹede Afirika to ti gba ife ẹyẹ naa ri.