Àgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bishop Wale Oke: Ìjọba kò gbọ̀dọ̀ gbè lẹ́yìn ẹ̀sìn kan

Alufa agba ijọ Sword of the Spirit ti iya ijọ rẹ kalẹ si ilu Ibadan, Biṣọọbu Francis Wale Oke gba ẹnu àwọn àlùfáà Nàìjíríà sọ̀rọ̀ nipa ohun ti Oloye Oluṣẹgun Obasanjo sọ pe gbogbo ipaniyan awọn Boko Haram ati ti awọn Fulani daran daran jẹ ọgbọn ati sọ Naijiria di ilu ẹlẹsin musulumi nikan.

Wale Oke ni Obasanjo kii ṣe ọmọde rara ninu iriri nipa orilẹede Naijiria nitori naa, ohun to ba sọ, ohun to ri ni.

Alufa naa ni daju daju Ọlọrun lo gba ẹnu Obasanjo sọ ọrọ yii tori ohun ti awọn alufa ti n tẹnu mọ lati ọjọ yii gan ni Obasanjo ṣẹṣẹ sọ jade yii.