Champions League: Ronaldo ní Tottenham yóò jẹ moyó ìyà lọ́wọ́ Liverpool

Ronaldo de Lima Image copyright Twitter/UEFA Champions League
Àkọlé àwòrán Champions League yoo yeruku lala

Ọ ní wọn á jìyà nínú àṣekágba ìdíje UEFA Champions League.

Ẹnu agba lobi tii gbo ni ọrọ Ronaldo lori idije Champions League yii.

Agbabọọlu fun orilẹ-ede Brazil tẹlẹ ri, ẹlẹsẹ ayo, Ronaldo ti inagijẹ rẹ n jẹ ''The Phenomenon'' ti sọ pe Liverpool yoo fagba han akẹgbẹ wọn, Tottenham ninu aṣekagba idije UEFA Champions League ti yoo waye lọjọ Abamẹta.

Ko da Ronaldo tun sọ pe ami ayo mẹta si ẹyọ kan ni Liverpool yoo fi la Tottenham mọ lẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun ti yoo waye niluu Madrid.

Ronaldo jẹ ọkan lara awọn atamatase ẹlẹsẹ ayo ti ko gba ife ẹyẹ Champions League ri, bo tilẹ je pe o ṣoju awọn ikọ agbabọọlu to lamilaaka ko to fẹhin ti ninu ere bọọlu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Ronaldo de Lima gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu Real Madrid fun ọdun marun un ṣugbọn ko ri ife ẹyẹ Champions League, ko da o tun ṣoju Barcelona naa fun ọdun kan.

Liverpool fiya jẹ Tottenham lẹẹmeji ti wọn ti koju Tottenham ni saa bọọlu yii.

Ronaldo ni Liverpool lo to gbangba sun lọyẹ, o si gbagbọ pe didun ni ọsan yoo so fun wọn nigba ti wọn ba koju Tottenham ni papa iṣere Wanda Metropolitano lọjọ nirọlẹ ọjọ Abamẹta.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMakinde: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ faramọ́ wíwọ́gilé ₦3000 táwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ń san

Eyi ni igba keji ti akọnimọọgba Jurgen Klopp yoo gbe ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool de ipele aṣekagba idije UEFA Champions League lẹyin Real Madrid gba ife naa mọ wọn lọwọ ni saa to lọ.

Liverpool ti gba ife ẹyẹ Champions League nigba marun un ọtọtọ, ṣugbọn igba akọkọ ree ti Tottenham yoo de ipele aṣekagba idije Champions League.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBarister lo bi gbogbo oníṣẹ́ fújì -Oṣupa