Champions League Final: Liverpool dín dòdò ìyà ṣínu ààwẹ̀ fún Tottenham

Jordan Henderson Image copyright Getty Images

A kii ṣẹgbẹ yin! Ọrọ ti ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool sọ fun Tottenham niyii lẹyin ti wọn fimu wọn fọn feere ninu aṣekagba idije UEFA Champions League niluu Madrid lorilẹede Spain.

Ami meji sodo ni Liverpool fi ṣagba Tottenham, ti wọn fi gba ife ẹyẹ naa fun igba kẹfa ninu itan ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Ẹlẹsẹ ayo, Mohammed Salah lo gbayo akọkọ sawọn fun ikọ Liverpool lẹyin iṣẹju meji pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun.

Divock Origi to wọ le fun Roberto Firmino lo gba goolu keji sawọn fun ikọ LIverpool.

Ere bọọlu naa ko ri bi ọpọ ti ro pe yoo rii, ko da Roberto Firmino ni lati jade fun Divock Origi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Liverpool lu Tottemham pa

Ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham gbiyanju, ṣugbọn omi pọ ju ọka lọ.

Liverpool fagba han Totenham

A da ọjọ, ọjọ pe, a da igba, oni ọjọ kinni, oṣu kẹfa ni a o mọ ẹni ti yoo sunkun ati ẹni ti yoo gba ife UEFA Champions League ti saa yii laarin Liverpool ati Tottenham.

Papa iṣere ẹgbẹ agbabọọlu Atletico Madrid, Wanda Metropolitano niluu Madrid tii ṣe olu ilu orilẹ-ede Spain ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ti waye.

Liverpool fiya jẹ ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lati pegede fun aṣekagba idije Champions League, nigba ti Tottenham fagba han Ajax lati wọ ipele aṣekagba.

Ọpọ awọn agbabọọlu ni wọn ti n sọrọ nipa ifẹsẹwọnsẹ alẹ oni wi pe yoo yeruku lala niluu Madrid.

Image copyright Twitter/UEFA Champions League
Àkọlé àwòrán Idije Champions League ti saa 2019

Gbajugbaja agbabọọlu Brazil tẹlẹ ri, to tun figba kan gba bọọlu jẹun ni ikọ agbabọọlu Real Madrid ati Barcelona, Ronaldo de Lima sọ pe ko si ani-ani kankan pe Liverpool yoo gbẹyẹ lọwọ Tottenham pẹli ami ayo mẹta si ẹyọ kan.

Diego Milito to gba ife ẹyẹ Champions League pẹlu Inter Milan lọdun 2010 ni tirẹ sọ pe Tottenham loun dibo fun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije UEFA Champions League

Milito ni Tottenham yoo ṣe ohun ti wọn fun Ajax fun Liverpool naa, o ni ami ayo meji sẹyọkan ni Tottenham yoo fi bori Liverpool.

Harry Kane ni ẹlẹsẹ ayo fun Tottenham nigba ti Mohamed Salah si jẹ ẹlẹsẹ ayo fun Liverpool.

Goolu mejilelogun ni Kane gba sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrindilogoji to gba, goolu mẹrindinlọgbọn ni Salah gba sawọn ni tirẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọta to gba.

Ṣugbọn ta ni yoo gba goolu sawọn lalẹ oni laarin awọn mejeeji ni papa iṣere Wanda Metropolitano niluu Madrid?