France 2019: orílẹ̀-èdè Adulawọ mẹ́ta ló n lọ ṣojú Afirika

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Asisat Oshoala maa gba bọọlu fun Naijiria

Orilẹ-ede France lo maa gbalejo awọn agbabọọlu obinrin ni gbogbo agbaye lọdun 2019.

Ọjọ keje, oṣu kẹfa ni idije ife ẹyẹ agbaye fawọn agbabọọlu obìnrin naa a bẹrẹ.

Naijiria, South Africa ati Cameroon ni orilẹ-ede mẹta to maa ṣoju ilẹ Adulawọ lapapọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAsisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Ikọ agbabọọlu mẹrinlelogun lo n ṣoju orilẹ-ede merinlelogun ti wọn yoo jọ dije gba ife ẹyẹ ti 2019 naa.

Ni Lyon ni France ni papa iṣerẹ ti wọn yoo ti gba aṣekagba idije naa lọjọ keje, oṣu keje, ọdun 2019.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ọkan gboogi ninu papa iṣere ti wọn ti maa figagbaga ni France

Papa iṣere mẹsan an ni ilu mẹsan an ọtọọtọ ni wọn a ti gba bọọlu naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oshoala ti Nigeria ati Thembi ti South Africa naa yoo kopa

Papa iṣere Parc Des Princes to jẹ ile fun Paris St-Gwermain ni wọn yoo ti gba idije ibẹrẹ ti wọn yoo fi ṣide ni France.

Papa iṣere Parc Olympique Lyonnais ti wọn tun n pe ni Groupama ni wọn yoo ti gba aṣekagba.

Papa iṣere yii ni wọn ti gba aṣekagba idije Europa League.

Oun naa ni wọn tun maa lo fun Summer Olympics to m bọ ni 2024.