CAF: Wo ohun tuntun tó n ṣẹlẹ̀ lágboolé CAF

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fatma, akọwe FIFA; Infantiano aarẹ FIFA ati Ahmad, aarẹ CAF

Ajọ agbaye to n risi ọrọ idije bọọlu alafẹsẹgba ti yan aṣoju tuntun.

Fatma Samoura to jẹ akọwe agba fun FIFA ni wọn yan pe ko lọ mojuto ọrọ CAF.

Confederation of African Football to jẹ ajọ bọọlu alafẹsẹgba ti ilẹ adulawọ ni awọn eeyan ti n fẹsun oriṣiiriṣii kan.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fatma ti Senegal gboye tuntun ni FIFA

Fatma to jẹ ọmọ ilẹ Senegal ni wọn ni ko maa ṣakoso CAF foṣu mẹfa lati ọjọ kinni, oṣu kẹjọ ọdun yii lọ.

Bakan naa ni wọn ni ko ṣe iwadii awọn ẹsun ti wọn n sọ nipa ajọ agbabọọlu ilẹ Adulawọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFídíò BBC yọ àwọn èèyàn FIFA níṣẹ́ ṣááju Russia 2018

Wọn tun ni ki Fatma ṣi maa ṣe iṣẹ akọwe ajọ FIFA lọ ṣugbọn o lè ya diẹ ninu iṣẹ rẹ fawọn oluranlọwọ.

Ajọ FIFA ni igba akọkọ ti awọn maa gbe iru igbesẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAsisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Aarẹ CAF, Ahmad Ahmad ni ẹnu ti n kùn loriṣiiri'sii lori ẹsun ni eyi ti oun naa ti ni oun ko jẹbi wọn.

Ni afikun, wọn ni ko mojuto ọrọ atungba idije bọọlu aṣekagba ti wọn sun si 2019, 2021 ati 2023.