AFCON 2019: Wo àwọn ẹranko tí wọ́n máa figagbaga ni Egypt

Àkọlé àwòrán Erin àti Ẹkun a gbéná wojú ara wọn ni Egypt

Ọpọlọpọ ẹranko nlanla lo maa pade ni idije AFCON to n bẹrẹ ni Egypt loni.

Eyi ni ẹlẹẹkejilelọgbọn iru rẹ nilẹ Adulawọ.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹrinlelogun to n ṣoju orilẹ-ede mẹrinlelogun ni yoo kopa ninu tọdun 2019.

A ni awọn kinihun oloola iju ti wọn n sọju orilẹ-ede wọn bii: Atlas Lions ni Morocco, Teranga Lions ti Senegal ati Indomitable Lions ni Cameroon.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFlorida: Ọ̀ọ̀nì àléègbà dé ba Mary lálejò lọ́gànjọ́ òru

Bakan naa ni a ni awọn ẹyẹ idì bii Super Eagles ti Naijiria, The Eagles ti Mali ati Carthage Eagles ti Tunisia.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eye maa gba bọọlu ni Egypt

Eyẹ Crane ni awọn Uganda fi pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn.

Ilẹ Afrika gbagbọ ninu agbara, ìṣe ati ihuwasi ẹranko ati ẹyẹ inu igbo pupọ yatọ si awọn ti Yuroopu ti wọn n fi orukọ à[wọ̀ pe ẹgbẹ ti wọn.

A tun ni ejo, Amọtẹkun ti DR Congo, Kọlọkọlọ ti Algeria ati awọn ẹranko mii ti yoo gori papa ni Egypt lọdun 2019 lati dije ninu ifẹ ẹyẹ AFCON to n bẹrẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFlorida: Ọ̀ọ̀nì àléègbà dé ba Mary lálejò lọ́gànjọ́ òru

Ọkẹrẹ ni ti Benin nigba ti Ivory Caost yan Erin lakatabu laayo.