Nàíjíríà yóò gba ife ẹ̀yẹ AFCON 2019 tí Super Eagles bá ṣe ara wọn ní ọ̀kan - Joseph Yobo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

AFCON 2019: Inú mi dùn pé mo jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó ṣojú Nàíjíríà fún ìgbà 100

Iriri lo n jẹ́ agba, ko si se fi owo ra.

Balogun tẹlẹ fun ikọ agbabọọlu Super Eagles , Joseph Yobo ti fọwọ sọya pe didun lọ̀san yoo so fun ikọ agbabọọlu ilẹ wa naa.

Yobo ni tawọn ikọ asoju Naijiria ni AFCON 2019 ba lee se ara wọn lọkan, ti wọn gba bọọlu pẹlu irẹpọ, ti wọn si ri ara wọn bii ẹbi kansoso, wọn yoo gba ife ẹyẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni Yobo ni inu oun dun lati jẹ agbabọọlu akọkọ ti yoo soju orilẹ́ede Naijiria ninu ere bọọlu fun igba ọgọrun.