AFCON 2019: Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù 24 ni yóò kópa nínú rẹ̀

Aworan ife ẹyẹ AFCON Image copyright Getty Images

Niṣe ni eto aabo duro deede ni olu ilu Egypt, Cairo ni ọjọ Ẹti ti ayẹyẹ iṣide idije ilẹ Africa, AFCON 2019 bẹrẹ.

Eyi ṣeeṣe ko ribẹ nitori bi eto aabo ṣe ri l'orilẹede naa bayi, latari bi aarẹ orilẹede naa nigba kan, Mohammed Morsi ṣe ku nile ẹjọ lasiko to n jẹjọ, ti idije naa si n waye lẹyin ọjọ diẹ ti eyi waye.

Gẹgẹ bi iroyin to n lọ labẹle, awọn oṣiṣẹ alaabo to to ẹgbẹrun mẹẹdogun ni yoo ṣiṣẹ ni awọn ilu mẹrẹẹrin ti idije naa yoo ti waye; Cairo, Alexandria, Suez ati Ismailia.

Bakan naa ni ibudo ayẹwo pọ yika papa iṣere ti eto naa ti waye lalẹ ọjọ Ẹti.

A gbọ pe eto ayẹwo kan tun ti wa nilẹ, lati maa tọ pinpin awọn oluworan lati igba ti wọn ba ti wọ papa iṣere, titi wọn yoo fi jade.

Fẹmi Kuti wa lara awọn akọrin ti yoo side AFCON 2019

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije AFCON tọdun 2019 ni igba kejilelọgbọn ti idije naa yoo waye.

Femi Kuti, tii se ọmọ Kaarọ Oojire, to tun jẹ ilumọọka akọrin lati orilẹede Naijiria, yoo dara pọ mọ awọn gbajugbaja akọrin miran, ti yoo ma a bawọn si idije bọọlu fun ife ẹyẹ ilẹ Afirika, AFCON 2019 pẹlu orin.

Orin kikọ̀ naa wa lara awọn ayẹyẹ ibẹrẹ idije Afcon naa, ti ọpọlọpọ ayẹyẹ ti yoo gbe asa ga ni ilẹ Afirika yoo rinlẹ nibi ayẹyẹ iside idije naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tani Femi Kuti ti yoo kọ orin iside Afcon 2019?

  • Femi kuti ni akọbi gbajugbaja akọrin kan ni ilẹ Afirika, Fela Anikulapo Kuti, ẹni to ja fun ẹtọ awọn ọmọ Naijiria ni ipasẹ orin kikọ nigba aye rẹ
  • Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Kẹfa, ọdun 1962 ni wọn bi Femi Kuti, ti wọn pe orukọ rẹ ni Olufela Olufẹmi Anikulapo Kuti
  • Ọdun 1977 ni Femi ti bẹrẹ si ni tẹlẹ baba rẹ kọrin, lẹyin ti iya rẹ kọ baba rẹ silẹ lati kekere
  • Bí i baba rẹ, Femi ma n lo orin lati fi se moriwu fun awọn eniyan, ki atunse le deba ilẹ Afirika
  • Moriya ti orin rẹ sẹ fun awọn eniyan lo se mu ki wọn fi orukọ silẹ fun Grammy Awards lọdun 2003, 2010,2012 ati 2013
  • Ni ọdun 2017, ni Femi Kuti lamilaaka julọ ni agbaye lẹyin to fun fere fun isẹju mọkanlelaadọta o le
  • Femi Kuti lo ni gbagede orin ti wọn n pe ni ‘the Shrine’, ti o wa ni ilu Eko, ni Naijiria.

Orúkọ àwọn orílẹ̀èdè tí yóò kópa ní AFCON 2019 rèé

Idije ti AFCON tọdun yii lo tobi ju lati ọdun 1957 to ti bẹrẹ. Ẹgbẹ agbabọọlu mẹrindinlogun ni yoo kopa fun igba akọkọ.

Bakan naa fun igba akọkọ, idije naa to maa n waye laarin oṣu Kinni ọdun si oṣu Keji yoo waye, laarin oṣu Kẹfa ọdun si oṣu Keje.

Image copyright Getty Images

Eyi waye nitori bi o ṣe maa n fa ariyanjiyan laarin igbimọ ajọ to n mojuto idije naa, CAF ati awọn ẹgbẹ agbabọọlu nilẹ Yuroopu, to ni lati yọnda awọn agbabọọlu wọn fun idije naa lai jẹ pe saa bọọlu gbigba nilẹ Yuroopu ti pari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn ninu oṣu Keje ọdun 2017, ajọ CAF pinnu lati sun idije ti ọdun yii si oṣu Kẹfa ati ikeje.

Bakan naa ni wọn sọ ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo kopa si mẹrinlelogun. Ẹgbẹ agbabọọlu mẹrindinlogun lo maa n kopa tẹlẹ.

Orilẹede Egypt lo gbalejo idije naa bayii fun igba karun un. Ẹgbẹ agbabọọlu Pharaoh ti Egypt si lo ti gba ife ẹyẹ idije naa ju lọ. O ti gba a fun igba meje.

Orilẹede Cameroon lo yẹ ko gba alejo idije AFCON 2019, ṣugbọn wọn gba a kuro lọwọ wọn l'oṣu Kọkanla, ọdun 2018, nitori pe wọn ko jara mọ imurasilẹ ati eto aabo to mẹhẹ l'orilẹede naa.

Oṣu Kinni ọdun 2019 ni ajọ CAF kede Egypt pe oun ni yoo gbalejo idije naa.

Awọn orilẹede ti yoo kopa ninu idije naa ni Egypt, Madagascar, Tunisia, Senegal, Morocco, Nigeria, Uganda, Mali, Guinea, Algeria, Mauritania, Ivory Coast, Kenya, Ghana, Angola, Burundi, Cameroon, Guinea-Bissau, Namibia, Zimbabwe, DR Congo, Benin, Tanzania, ati South Africa.