Ọmọ Naijiria, ẹ ṣọ́ra lórí ọ̀rọ̀ Ebola
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ebola Virus: ìdí tí Ebola fi ń tàn kálẹ̀

O lé ni ènìyàn 28, 000 tó ti gbẹmi mi lori ọrọ Ebola.

Ebola tun ti pada si ilé Adulawọ.

O tun ti de si orilẹ-ede DR Congo ati Uganda pada.

Loṣu keje, ọdun 2014 ni Naijiria kọkọ kagbako ọrọ arun Ebola.

Eniyan mẹjọ lo kọkọ ba iṣẹle yii rin ninu awọn ogun eniyan to kọkọ kọlu.

Arakunrin Patrick Sawyer to jẹ ọmọ orilẹ-ede Liberia lo kó ebola wọ Naijiria.

Iwadii fihan pé arun ebola tun n pada wa silẹ Adulawọ nitori pé awọn eeyan ilẹ Afrika kii ye jẹ ẹran igbẹ.

Wọn ni arun ebola wa lara awọn ẹran igbẹ bii igala, inaki, ọbọ lagido ati adan.

Awọn onimọ ni imọtoto ṣe pataki lawujọ ki arun gbogbo ma le ṣe akoba fawọn eniyan.