AFCON 2019: Àwọn ikọ̀ Super Eagles ti gbà lára owó àjẹmọ́nú wọn

Awọn agbabọọlu Ṣuper Eagles Image copyright AFP

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu sisan lara owo ajẹmọnu awọn ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti Naijiria.

Aarẹ Buhari gbe igbesẹ yii lẹyin ti awọn agbabọọlu yii ko jalẹ wi pe awọn ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Burundi ninu idije Afcon 2019 ti ijọba ko ba san awọn owo ajẹmọnu ti wọn jẹ wọn.

Awọn ẹgbe agbabọọlu naa ko lati lọ fun ipade ti wọn ma n se saaju ifẹsẹwọnsẹ. Bakan naa ni wọn pe de ibi ti wọn ti se igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye ni oni.

Igbakeji aarẹ ajọ to n risi ọrọ erebọọlu ni Naijiria, Seyi Akinwunmi lo fi idi ọrọ naa mulẹ pe ajọ naa pa lara owo ajẹmọnu wọn ni owurọ Ọjọ Isegun, ti ohun gbogbo si ti pada si ipo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInternational Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró

Kò s'òwó, kò sí ìgbáradì fún ìdíje pẹ̀lú Guinea - Super Eagles fárígá

Awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu agba Naijiria, Super Eagles kọ lati gbaradi fun idije ti yoo waye laarin wọn ati ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Guinea l'ọjọru ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika to n lọ lọwọ ni Egypt.

Image copyright AFP

Awọn agbabọọlu naa yari nitori pe wọn ko ti i gba awọn ajẹmọnu wọn.

Awọn agbabọọlu naa ko ti i gba ẹgbẹrun mẹwaa Dọla, to yẹ ko jẹ owo ajẹmọnu fun pe wọn dije, ti wọn ṣe ileri rẹ fun ẹnikọọkan wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibayii, ajọ to n risi ere bọọlu ni Naijiria, NFF, ti n gba gbogbo ọna lati wa owo, ki awọn agbabọọlu naa ma ba a da iṣẹ silẹ.

Olori akọnimọọgba wọn, Gernot Rohr, sọ nibi ipade akọroyin kan pe

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInternational Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró

'Ireti mi ni pe wọn yoo tete yanju ọrọ to wa nilẹ yii, ka le gbajumọ iṣẹ to wa niwaju wa.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

'Mo mọ pe awọn agbabọọlu naa ti gbaradi nipa ti ara, lai fi ti pe wọn n ṣaisan tabi farapa ṣe. Ṣugbọn, ọrọ ajẹmọnu yii n da omi tutu si wọn lọkan.''

BBC ri gbọ pe, ileri ẹnu loriṣiriṣi ni ikọ Super Eagles ri gba pe, wọn yoo san awọn owo ajẹmọnu fun wọn ki idije AFCON to o bẹrẹ ni Egypt.

Amọ ṣa, ọsẹ kan ti pe bayii, ti ẹnikẹni ninu wọn ko si ti i ri 'kọbọ' gba.

Ọpọ igba ni awuyewuye maa n waye lori owo awọn agbabọọlu Naijiria.

Awọn akọnimọọgba wọn kii gba owo deede, bẹẹni awọn agbabọọlu ti kọ lati lọ fun igbaradi lasiko awọn idije komẹsẹoyọ (qualifiers) tabi ni awọn idije pataki nitori airi owo ajẹmọnu gba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAFCON 2019: Inú mi dùn pé mo jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó ṣojú Nàíjíríà fún ìgbà 100

Ẹẹmeji ọtọọtọ ni awọn agbabọọlu obinrin, Super Falcons naa fi ẹhonu han nile itura ni South Africa ati Abuja lati beere fun owo ti wọn jẹ wọn.

Iroyin tilẹ sọ laipẹ yii pe, wọn kọ lati kuro ni ile itura lẹyin ti wọn ja kuro ni idije ife agbaye awọn obinrin to n lọ lọwọ ni France, nitori ọrọ yii kan naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen