Àgùnbánirọ̀ gbẹ́mìí mì látàrí 'Snipper' tó fi fọ irun rẹ̀

Ayomikun Juliana Image copyright Ayomikun Juliana

Ayomikun Ademorayo Juliana tó jẹ agunbanirọ to n sin ilẹ̀ baba rẹ nipinlẹ Ọṣun ti doloogbe.

Lọjọ Aiku to kọja niroyin ni o jade laye lẹyin igbiyanju rẹ lati pa iná orí to wa ninu irun rẹ.

Awọn ti wọn jọ n ṣe agunbanirọ ni ile iwe ikọni Tai Solarin lo ti pari ẹkọ rẹ ko too wa sin ilẹ̀ baba rẹ, ko to o jade laye.

Wọn ṣalaye pe lasiko to n gbiyanju lati tu irun to ṣe tẹlẹ ni imurasilẹ ọjọ ìbí rẹ to m bọ lọna ni o kofiri ina ori ninu irun rẹ.

Awọn akẹgbẹ rẹ ni bi o ṣe fi oogun apakokoro Snipper sinu irun ori rẹ lo de e pe ki o le pa awọn kokoro ina inu irun naa.

Gbogbo igbiyanju wọn lati doola ẹmi rẹ nile iwosan lo pada ja si pabo.

Image copyright @juliana
Àkọlé àwòrán Iku doror ni ipinlẹ Osun

Nigba ti BBC kan si ajọ to n mojuto ọrọ awọn agunbanirọ ni Oṣogbo to jẹ olu ilu ipinlẹ Oṣun, ni wọn fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Agbẹnusọ ajọ NYSC ṣalaye fun BBC Yoruba pe lootọ ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ati pe awọn ti kan si obi agunbanirọ naa.

Ati pe awọn ti fi iṣẹlẹ yii to olu ile iṣẹ Agunbanirọ to wa ni Abuja leti bi o ti yẹ labẹ ofin.

Related Topics