Asamoah Gyan lè má kópa nínú ìdíje AFCON mọ lẹyìn tí Tunisia júwe ilé fún Ghana

Aworan Asamoah Gyan Image copyright @SaddickAdams
Àkọlé àwòrán Gyan ni ko daju pe oun yoo kopa ninu idije Afcon mi mọ

Niṣe ni ibanuje dori agba kodo lẹyin ifidirẹmi Ghana lọwọ Tunisia fawọn agbabọọlu ati alatilẹyin ikọ Black Stars.

Gbajugbaja atamatase ikọ naa ti o jẹ Balogun Kaafata Black Stars Asamoah Gyan ko tilẹ mọ boya oun yoo tun kopa ninu idije AFCON mi mọ lẹyin ijakulẹ yi.

O sọrọ yi fawọn oniroyin lẹyin ifidirẹmi Ghana lọwọ Tunisia ninu idije AFCON to n lọ lọwọ ni orilẹ-ede Egypt.

''O ṣeeṣe ki n ma kopa ninu AFCON imiran mọ. Mi o le sọ; Amọ, o le jẹ AFCON ti maa gba kẹyin ree''

Idije AFCON ti Egypt yi ni igba ẹlẹẹkeje ti Gyan yoo kopa, ọdun 2008 ti Ghana gbalejo idije naa lo kọkọ kopa ninu AFCON.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn to n bá ẹlẹkun sunkún ní Ghana

Kii ṣe Gyan nikan ni ọrọ yi so si lẹnu to tun buyọ si.

Aarẹ orile-ede Ghana, Nana Akufo Addo naa ba ọkan jẹ lori ijakulẹ yi amọ ṣa o loun ni ireti pe Ghana yoo gberasọ pada.

Lorile-ede Ghana lowurọ ọjọ Isẹgun, ọrọ kan ti yoo ma ja ranyin ranyin ni eleyi to nii ṣe pẹlu ifidirẹmi ikọ agbabọọlu Black Stars lọwọ Tunisia ninu idije AFCON.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIya Woli: Ẹ̀mí ìjókíjó, Wòó, Ṣọ̀kí, Wojú, Ṣàkùṣákù, One Corner...jáde!

Pupọ ninu awọn ọmọ orile-ede naa ni o ti n faraya lori ijakulẹ́ yi ti awọ́n miran si ni ki wọn gba iṣẹ́ lọwọ aknimọọgba ikọ naa, Akwasi Appiah

Amọ o jọ bi ẹni pe awọn ọmọ Naijiria n dunnu si ohun to de ba Ghana yi.

Loju opo Twitter ọrọ yẹyẹ gbẹnu awọn ọmọ Naijiria kan lori bi Ghana ti ṣe kogba wọle ninu idije AFCON yi

Orile-ede Ghana ti o ti gba ife ẹyẹ AFCON lẹmẹẹta ọtọọtọ wa lara awọn to ro pe wọn yoo gba ife eye naa ṣugbọn ti ijakulẹ ba wọn.

Egypt to n gbalejo idije naa ati Cameroon to gba ife ẹy naa ninu idije to kọja ti di ero ile bakan naa.

Ni bayi, Naijiria, Senegal, Madagascar, South Africa, Algeria, Ivory Coast,Tunisia ati Benin ni yoo kopa ninu abala to kan.

Lọjọ kẹwaa oṣu yi ni Naijiria yoo pade South Africa ni ilu Cairo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀