AFCON 2019: Ṣìṣeṣìṣe Troost-Ekong ṣokùnfà ìyà àjẹsùn fún Nàìjíríà lọ́wọ́ Algeria

Riyad Mahrez ati Super Eagles Image copyright Getty Images

Super Eagles gbiyanju, ṣugbọn omi pọ ju ọka lọ, ami ayo meji ni Algeria fi ṣe wọn leegun ẹyin lalẹ ọjọ Aiku minu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba ninu idije AFCON.

Ṣiṣeṣisẹ ba adilemu, William Troost-Ekong, lo ba gba bọọlu sawọn Naijiria nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun de ogoji iṣẹju.

Ṣugbọn ẹlẹsẹ ayo Odion Ighalo dayo naa pada ni abala keji ere bọọlu ọhun.

Amọ, agbaọjẹ agbabọọlu Algeria, Riyad Mahrez ṣẹ ikọ agbabọọlu Naijiria leegun ẹyin lẹyin to gbayo keji wọ le fun Algeria ni iṣẹju ti ere bọọlu naa pari.

Image copyright Twitter/Super Eagles
Àkọlé àwòrán Naijiria fidi rẹmi

Ni bayii, Naijiria yoo koju Tunisia l'Ọjọru lati ja fun ipo kẹta, nigba ti Algeria yoo ta kangbọn pẹlu Senegal ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije AFCON 2019.

Super Eagles kò ní já àwọn ọmọ Nàìjíríà kulẹ̀- Musa

Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles sọ pe awọn ti ṣetan lati jẹwọ ara awọn fun ikọ agbabọọlu South Africa ninu ifẹsẹwọnsẹ ipele ẹlẹni mẹjọ lalẹ Ọjọru.

Ẹlẹsẹ ayo, Ahmed Musa ni awọn ko ni ja awọn ololufẹ awọn ọmọ Naijiria kulẹ nigba tawọn ba n koju Bafana Bafana.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà ti já ní AFCON

Musa ni awọn mọ pe awọn ọmọ Naijiria fẹran ere bọọlu gan an, o ni awọn ti ṣetan lati pa wọn lẹrin.

O ni awọn agbabọọlu Naijiria ko ro nnkan miiran bayii ju bi wọn yoo ṣe fiya jẹ South Africa lọ.

Image copyright Instagram/William Troost-Ekong

Musa sọ pe awọn duro digbi fun ohun kohun ti Bafana Bafana ba fẹ gbe wa.

Igba mẹrinla ni Naijiria ati South Africa ti pade ara wọn.

Naijiria jawe olubori nigba mejila ọtọọtọ, ti South Africa si jawe olubori nigba kan.