AFCON 2019: Ṣé Super Eagles yóò rí agbábọ́ọ̀lù tí yóò mú ìyàtọ̀ wá bí Bright Omokaro ṣe ṣe ní Maroc '88?

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Ṣé o rántí itú tí Bright Omokharo fi Algeria pa ní MAROC '88?

Orilẹ-ede Naijiria yoo koju Algeria loni ninu ifẹsẹwọnsẹ ipele to kangun si aṣekagba idije AFCON 2019 to n lọ lọwọ ni Egypt.

Gẹgẹ bi a ti ṣe sọọ ṣiwaju, igba akọkọ kọ niyi ti awọn orilẹ-ede mejeeji yii yoo maa fi ori gbari ni idije naa.

Gbogbo igba ti wọn ba si ti waako ni awọn ololufẹ ere bọọlu maa n ri awọn ohun manigbagbe di mu.

Lara awọn ohun manigbagbe naa, eleyii to waye lasiko ti wọn pade ni ipele to kangun si aṣekagba yii kan naa ni tọdun 1988 ni a mu wa fun un yin yii.

MAROC '88; eyi kọja bẹ́ẹ̀

Agbabọọlu ọmọ Naijiria nigba kan ri, Bright Omokharo ti ọpọ mọ si 'Ten-Ten' ni a fẹẹ lee tọka si gẹgẹ bii agbabọọlu ilẹ yii ti egungun rẹ le julọ ninu iwe itan.

Adele ọwọ ọtun ni Ọmọkharo, idije ife ẹyẹ ilẹ Afirika, Maroc 88 ni o si ti gba inagijẹ yii ninu ifẹsẹwọnsẹ laarin orilẹ-ede wa Naijiria ati orilẹ-ede Algeria.

Alamojuto idije naa ti kọkọ fun agbabọọlu Naijiria, Ademọla Adeshina ni kaadi pupa to si lee jade eleyi to sọ ikọ Naijiria di agbabọọlu mẹwaa.

Olukọni ikọ Super Eagles nigba naa, Manfred Hoener wa fi eeni ko eeji, lo ba ni ki Omokharo o wọle. Njẹ ẹ mọ ohun to sọ fun un ki o to wọle?

"Ṣe o mọ pe elegungun lile ni ẹ, mo fẹ ki o lo egungun yii daradara"

Ni kete ti Omokharo wọle lo ti kan agbabọọlu Algeria kan leegun ti wọn si gbe onitọhun jade wọn ko si lee rọpo rẹ mọ nitori iye irọpo to yẹ ni ṣiṣe ni ikọ Algeria ti ṣe tan nigba naa ki o to ṣẹlẹ.

Eyi lo mu ki akaroyin Oloogbe Earnest Okonkwo to n ṣalaye nipa bọọlu naa lọjọ naa lọhun o pariwo o

"Omokharo ti sọ idije toni di mẹwaa-mẹwaa o (Ten-Ten )" Ọrọ yii lo si gba oju ewe iwe iroyin gbogbo ni ọjọ keji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIya Woli: Ẹ̀mí ìjókíjó, Wòó, Ṣọ̀kí, Wojú, Ṣàkùṣákù, One Corner...jáde!

Orilẹ-ede Naijiria ati Algeria yoo tun maa figagbaga loni, awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, paapaa julọ awọn ololufẹ ere bọọlu ni wọn ti n foju sọna lati mọ ewo ninu awọn agbabọọlu ikọ Super Eagles ti yoo mu iyatọ wa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

A kò ṣẹ̀ṣẹ̀ jọ máa pàdé ara wa! Wo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn...

Aago mẹ́jọ alẹ oni ọjọ kẹrinla, oṣu keje ni lala o lu ti pẹpẹyẹ maa pọnmọ laarin Naijiria àti Algeria.

Awọn ikọ agbabọọlu orilẹ-ede mejeeji yii jọ pegede ninu idije ẹlẹni mẹrindinlogun ti AFCON to n lọ lọwọ ni orilẹ-ede Egypt.

Awọn mejeeji ni yoo jọ waako lalẹ oni ọjọ Aiku ti wọn yoo fi mọ ẹni to n lọ si ipele aṣekagba idije ifẹsẹwọnsẹ tilẹ Adulawọ fun ọdun 2019.

O ti to ọdun marundinlaadọta sẹyin ti ikọ agbabọọlu mejeeji ti jọ n kọlu ara wọn ninu idije ere bọọlu alafẹsẹgba,

Ṣe ti ọmọ ko ba ba itan, o yẹ ko ba arọba to jẹ baba itan koda ninu idije ere bọọlu.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin laarin Algeria ati Naijiria?

Ikọ agbabọọlu Super Eagles ti Naijiria ti gba ife ẹyẹ yii lẹẹmẹta sẹyin ni eyi ti wọn dẹ tun fẹ fi tọdun 2019 ṣe ikẹrin wọn.

Odun 1980 ni wọn kọkọ gba alakọkọ nigba ti awọn ati Algeria jọ na an tan bi owo.

Ikọ agbabọọlu Desert Foxes ti Algeria naa ni awọn ko ni gba a laabọ lalẹ oni fun Super Eagles rara.

Awọn naa fẹ gbe ife ẹyẹ AFCON 2019 lọ lẹẹkeji.

Eẹkan ṣoṣo ti Algeria tii gba ife ẹyẹ yii ri ni ti idije ọdun 1990 ti wọn ti na Naijiria ni orilẹ-ede wọn.

Idije to pa awọn mejeeji pọ laipẹ yii ni nigba ti Naijiria koju Algeria ninu idije kikopa ninu ife ẹyẹ agbaye Russia 2018 to kọja.

Lọdun 2017 ni Naijiria na Algeria pẹlu ami ayo mẹta si ookan ni papa iṣerẹ Uyo ni ipinlẹ Akwa Ibom ni Naijiria.

Wọn dẹ jọ gba ọmi ookan si ookan ni Constantine ki FIFA to fun Algeria.

Igba mẹjọ ọtọọtọ ni Naijiria ti fagba han Algeria ninu idije sẹyin nigba ti wọn ti jọ gba ọmi ni ẹẹmarun un.

Algeria naa ti ṣokọ fun Naijiria lẹẹmeje ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn latẹyin wa.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Algeria pada ri maaki mẹta gba nitori Naijiria lo agbabọọlu ti wọn ti ni ko lọ rọọkun nile tẹlẹ.

10.03.1982 (Ipele ẹlẹgbẹjẹgbẹ) Benghazi Algeria 2-1 Nigeria

11.03.1984 (Ipele ẹlẹgbẹjẹgbẹ) Bouake Algeria 0-0 Nigeria

23.03.1988 (Semi - final) Rabat Nigeria 1-1 (9-8 kọju si goli ko o gbaa sile) Algeria

02.03.1990 Ipele ẹlẹgbẹjẹgbẹ) Algiers Algeria 5-1 Nigeria

16.03.1990 (Aṣekagba) Algiers Algeria 1-0 Nigeria

21.01.2002 Ipele ẹlẹgbẹjẹgbẹ) Bamako Nigeria 1-0 Algeria

30.01.2010 (ipo kẹta) Benguela Nigeria 1-0 Algeria

Algeria ni ko jẹ ki Naijiria pegede lati lọ fun idije ifẹ ẹyẹ agbaye lọdun 1982 nigba ti wọn na Super Eagles mọle.

Bakan naa ni wọn tun na Super Eagles ni ami ayo meji si ookan ninu idije ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti AFCON lọdun 1982.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán AFCON 2019: A kò ṣẹ̀ṣẹ̀ jọ máa pàdé ara wa! Wo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn...

Ọmi ayo ni wọn jọ gba lọdun 1984 ati 1988 nigba ti wọn jọ pade ki Naijiria to bori pẹlu goolu kọju si goli koo gba a si awọn.

Ninu idije AFCON tọdun 1990 ti Algeria gbalejo rẹ, ami ayo marun un si ookan ni wọn fi ṣina fun Naijiria ki wọn to gba ife lọ nigbẹyin.

Naijiria naa dena kikopa Algeria ninu idije 1988 tawọn ọkunrin nigba ti wọn bo idi Algeria pẹlu ami ayo meji sodo ni papa iṣere Enugu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌgbárùn ni ètò BB Naija kíì ṣe ìgbádùn - MURIC

Naijiria ni ko jẹ ki Algeria le kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye nigba ti wọn ṣina fun kọlọkọlọ Algeria pẹlu ami ayo mẹrin si ookan ni papa iṣere ipinlẹ Eko.

Bakan naa ni wọn tun na Algeria pẹlu ami ayo ẹyọ kan si odo nigba ti wọn pade ni idije AFCON 2002 ti Mali gbalejo ẹ.

Eyẹ idi Super Eagles fi Algeria gba ipo kẹta ninu idije AFCON ti orilẹ-ede Angola gbalejo ẹ lọdun kẹjọ to tẹlẹ ikọlu wọn miran.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ẹẹmeji ni Mahrez ti gba bọọlu sawọn ni idije AFCON

Kini igbagbọ awọn eniyan fun Super Eagles Naijiria?

Ọpọ gba pe o yẹ ki Naijiria le ṣina fun Algeria ninu idije ti alẹ oni nitori pe wọn ti ri asiko isinmi to pọ diẹ.

Ati pe idije ti Algeria gba kẹyin gbo wọn pupọ nitori wọn gba bọọlu pẹlu afikun asiko ki wọn to gba kọju si goli koo gba a si àwọn lọjọbọ to kọja.

Yatọ si eyi, igbagbọ wa pe o yẹ ki Super Eagles tun na Algeria gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe ninu idije kikopa fun ife ẹyẹ agbaye tọdun 2018 to kọja.

Algeria pada ri maaki mẹta gba nitori Naijiria lo agbabọọlu ti wọn ti ni ko lọ rọọkun nile tẹlẹ.

Sibẹ awọn ololufẹ Super Eagles ni ki wọn ṣora fún Adam Ounas ati Mahrez ti wọn jẹ agba ọjẹ agbabọọlu fun Algeria.