Russia Boxer: Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò dágbére fáyé lásìkó ìjà rẹ

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iku ogun lo pada pa akinkanju abẹṣẹkubiojo Maxim

Iroyin ni kete ti wọn pari ija naa ni o ti hande pe Maxim ko le da rin kuro ni gbagede ija.

Dadashev Maxim ọmọ Russia ni oun ati Subriel Matias jọ ja du bẹliti abẹṣẹkubiojo IBF light welterwiight.

Buddy McGirt to n dari rẹ lo ni ki wọn fopin si ija naa ni ipele ikọkanla lọjọ Eti nigba ti Maxim ko lagbara mọ.

Ni kete ti wọn lu aago yii ni wọn ti gbe Maxim lọ sile iwosan nitori ẹjẹ ti n dà ni agbari rẹ nibi ti wọn ti sare ṣiṣẹ abẹ fun un.

Lẹyin iṣẹ abẹ yii ni ko pada ji mọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lẹyin iṣẹ abẹ yii ni ko pada ji mọ.

Ajọ to n mojuto ọrọ ẹṣẹ kikan ni orilẹ-ede Russia ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii kikun lori iṣẹlẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSekinat Quadri ọmọ ọdun meje ajẹsẹ to fẹ dabi Anthony Joshua

Umar Kremlev to jẹ akọwe agba ajọ naa ni o dabi pe ejo iku Maxim fẹ lọwọ ninu.

O ni Maxim jẹ ọkan lara awọn ọdọmọde abẹṣẹku bi ojo ti Russia n wo fun ọjọ iwaju rere.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo ń ṣa ike jọ láti san owó ilé iwé ọmọ mẹ́ta'

Akọwe agba naa ni ajọ naa maa ṣatilẹyin to yẹ fun ẹbi Maxim pẹlu owo ati pe awọn yoo ṣe iwadii naa bi o ti yẹ.

O gba pe mimọ ootọ iṣẹlẹ yii yoo jẹ ki aato gidi wọ inu ere idaraya wọn gbogbo.

Orilẹ-ede Amerika ni Dadashev n gbe to ti gba ami ẹyẹ mẹtala nibi ija mẹtala to ti bori sẹyin.

Subriel Matias to jẹ ẹlẹṣẹ lati Puerto Rico lo ti na Maxim pupọ ni Maryland.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán A ju ara wa lọ, .....

McGirt to jẹ atọna rẹ ni oun n ni ko dẹkun ija nigba ti oun rii pe ọrọ fẹ maa bẹyin yọ.

Ajọ RBF ni Russia ni o n rẹ Dadashev sii nigba ti awọn oniṣegun oyinbo ni nkan ti ṣe ọpọlọ rẹ.

Lọjọ Iṣẹgun ni Maxim wa gbẹmi mi nigba ti ọkan re kọ iṣẹ lẹyin iṣẹ abẹ ti wọn ti ṣe fun un.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionChef Adefunkẹ: Òórùn ewé tí wọ́n n pọ́n ìrẹsì ọ̀fadà si jẹ́ adùn lọ́tọ̀