Transfer Window: Pogba, Maguire, Bale, Neyman, báwo ni nkan ṣe ń lọ?

Gareth Bale
Àkọlé àwòrán,

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ti ni ko si n to o jọ rara pe oun fẹ ẹ ra Gareth Bale

Manchester United ti n gbaradi de lilọ Paul Pogba kuro lọdọ wọn.

Wọn si ti fẹ ẹ fi ẹnu ko lori rira agbabọọlu orilẹ-ede Serbia, Sergel Milinkovic-Savic, ni aadọrin miliọnu Pọnun. (Mirror)

Amọ ṣa, o ṣeeṣe ki Pogba o ṣi lo ọdun kan si i ni Old Trafford, eyi to le mu ifasẹyin ba rira ti wọn fẹ ra Milinkovic-Savic. (Express)

Bakan naa ni o ṣeeṣe ko di dandan fun Manchester United lati wa ọgọrin miliọnu Pọnun ti wọn yoo fi ra agbabọọlu England, Harry Maguire lẹyin ti Eric Bailly fi orunkun ṣeṣe lasiko idije ọlọrẹsọrẹ pẹlu Tottenham ni Ọjọbọ. (Mirror)

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ti ni ko si n to o jọ rara pe oun fẹ ẹ ra Gareth Bale lati ọwọ Real Madrid.

O ni afojusun oun ni lati kọ ẹgbẹ agbọọlu to dantọ, kii kan ṣe lati ko eniyan jọ saa. (Independent)

O dabi ẹni pe ko si bi agbabọọlu iwaju fun Juventus ati Portugal, Cristiano Ronaldo ṣe mọ idunna-dura a ṣe to, ko ni le fi ọrọ yi atamatase Paris St-Germain, Neyman lọkan pada lati darapọ mọ idije Serie A, nitori o da bi ẹni pe Neyman ti pinnu lati pada si Barcelona. (Star)

Àkọlé àwòrán,

Barcelona lo wu Neyman ko pada si.

Borossia Dortmund naa ti n duna-dura lati ra ọmọ orilẹede Brazil, Malcom ni miliọnu mejilelogoji Euro. (Goal)

Akọnimọọgba Napoli, Carlo Ancelotti ni ọkan oun balẹ bi omi inu amu pe ẹgbẹ agbabọọlu oun ni yoo ra James Rodriguez lati ọwọ Real Madrid. (Marca)

Everton naa ti sọ fun Crystal Palace pe awọn ṣetan lati san ọgọta miliọnu Pọun fun rira atamatase orilẹ-ede Turkey, Cenk Tosun ni igba kan naa pẹlu Wilfred Zaha. Amọ aya wọn ṣi n ja pe o ṣeesẹ ki Chelsea o ja a gba mọ wọn lọwọ. (Telegraph)

Atamatase ni, Moussa Dembele naa yoo wa lara awọn to ṣeeṣe ki wọn o ta Romelu Lukaku. (Sky Sports)

Ẹgbẹ agbabọọlu Wolves naa ti n ba Real Madrid sọrọ lati ra Jesus Vallejo fun saa kan, nigba ti Real Madrid naa ti n sunmọ bebe ati fẹnuko lati gba miliọnu mẹtadinlogun Pọnhun lọwọ AC Milan lati ra atamatase, ọmọ orilẹede Italy Patrick Cutrone. (Mail)

Àkọlé fídíò,

Kayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó