Vincent Enyeama: Aṣọ́lé Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí ṣe tán láti padà sórí pápá

Vincent Enyeama Image copyright Instagram/Vincent Enyeama
Àkọlé àwòrán Enyeama n gbaradi lati darapọ mọ ikọ agbabọọlu tuntun

Aṣọle fun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri, Vincent Enyeama ti ṣe tan lati pada sori papa lẹyi ti ko ṣoju ikọ agbabọọlu kankan fun ọdun meji.

Enyeama wa pẹlu ikọ agbabọọlu ilẹ Faranse, Dijon nibi ti o ti n gbaradi fun ati pada sori papa.

Ẹgbẹ agbabọọlu Dijon fun Enyeama laye lati wa pẹlu wọn di ipari oṣu yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionN100,000 Nairà mà ni Dino gbé dání lójú agbo, kò náwó yàlà-yòlò - Ayefele

Lẹyin naa ni akọnimọọgba Stéphane Jobard yoo gbe igbesẹ bo ya Enyeama yoo dara pọ mọ ikọ Dijon.

Ọdun 2017 ni aṣọle Enyeama ṣoju ikọ agbabọọlu kẹyin lẹyin to fi ẹgbẹ agbabọọlu Lille silẹ loṣu kẹjọ ọdun 2018.

Image copyright Instagram/Vincent Enyeama
Àkọlé àwòrán Enyeama n gbaradi lati darapọ mọ ikọ agbabọọlu tuntun

Enyeama ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ ọgọrun o le kan.

Bakan naa lo mu 'le fun Naijiria ninu idije AFCON marun un ko to fi ikọ agbabọọlu Super Eagles silẹ.

O wa lara ikọ agbabọọlu Naijiria to gba ife ẹyẹ AFCON 2013 lorilẹede South Africa.