Kelechi Iheanacho ẹlẹ́sẹ̀ ayò tún ti dábírà fún Leicester City

Image copyright @Leisecter
Àkọlé àwòrán Eyi ti mo fẹ sọ bọọlu sawọn lẹẹmeji

Kelechi Iheanacho, ogbontarigi ninu awọn ọdọ agbabọọlu Naijiria tun ti jẹwọ orukọ rẹ.

Eemeji ọtọọtọ lo sọ bọọlu sáwọn ẹgbẹ agbabọọlu Rotherham nigba ti Leicester City pade wọn lọjọ Abamẹta.

Bi ẹ ko ba gbagbe, o ti le ni oṣu mẹwaa ti Iheanacho ti gba ami ẹyẹ goolu sẹyin ti ko si ri bọọlu kankan gba si awọn.

Inu awọn agbabọọlu Leicester City dun pupọ ni eyi ti o n fi ọkan wọn balẹ de idije Premier league to maa bẹrẹ lọjọ kẹsan an, oṣu kẹjọ, ọdun yii.