Man United vs Chelsea: Ajá to bá wọlé tí ẹkùn yóò fẹjẹ̀ wẹ̀

Manchester United ati Chelsea Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Man United vs Chelsea: Man U fí han Chelsea pe ajá to wọlé ti ẹkun yóò fẹ̀jẹ̀ wẹ̀

Manchester Unite ti fàgbà han Chelsea pe ẹni o ṣe lásìkò tí wọ́n kọlu ara wan nínu ìfẹsẹ̀wọ́nṣe ti wọ́n fi ṣide premiere League sáà yìí, pẹ̀lú àmi ayò mẹ́rì si òdo

Àmì ayò méjì ni Marcus Rashford fi sẹ ogun Frank Lampard nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́yìn to gba iṣẹ́ akanimọ̀ọ́gbá Chelsea àti àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ ní ìpele ìkíní àti ìkejì

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWolii Arole

Anthony Martial àti Daniel james náà ràn Red Devil lọ́wọ́ láti jáwe olúbori Chelsea ninu ìdíje tó dabi pé ó fẹ́ kó Chelsea lóyìí ojú.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Man United vs Chelsea: Man U fí han Chelsea pe ajá to wọlé ti ẹkun yóò fẹ̀jẹ̀ wẹ̀

Ìyàlẹ́nu ní abájáde ìfẹsẹwọnsẹ̀ ọ̀hun jẹ́ nítori ó jọ bi ẹni pé Chelsea yóò ṣe dáradár jú Manchester United lọ ní sáà àkọ́kọ́, bọ́ọ̀lù ṣe gbá àwsn pada ní ẹ̀ẹ̀mejì bi Emerson àti Tammy Abraham ṣe gbìyànjú tó.

O jọ bi ẹní pe àwọn olólùfẹ́ Manchester United ko ni fi bẹ́ẹ̀ ba Chelsea kẹ́dùn bí ìdíje yìí ṣe jẹ èsì tó tíì dára júlọ ni old Trafford pẹ̀lú Chelsea láti ọdun 1965

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí