Liverpool vs Chelsea: Lampard wọ gàu! Chelsea tún ṣubú dàánù lẹ́ẹ̀kan si

Awọn ọmọ Chelsea Image copyright Getty Images

Pàá lẹ́ẹ̀kínní, pàá lẹ́ẹ̀kejì! Ṣé ojú Frank Lampard àtàwọn agbábọ́ọ̀lù Chelsea tí wọ́n ń gbá lọ́tùn ún lósì kò ní fọ́ báyìí? Ẹ̀yin ọmọ Chelsea kí ló ǹ ṣẹlẹ̀ gan an?

Liverpool fi pẹnriti na Chelsea ninu idije UEFA Super Cup to waye niluu Istanbul lorilẹede Turkey.

Ami ayo pẹnariti marun un si mẹrin ni wọn fi ṣagba Chelsea lẹyin ti wọn ti kọkọ ta ọmi alayo mejemeji.

Igba keji ree ti Chelsea yoo fidi rẹmi laarin ọjọ mẹrin lẹyin ti Manchester United na wọn lọjọ Aiku ninuidije Premier League

Chelsea láǹfààní láti t'ọ́mọlúábí wọn ṣe pẹ̀lú Liverpool lálẹ́ òní

Iduro ko si ibẹrẹ ko si fun ẹni to gb'odo mi lọrọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea bayii, lẹyin ti wọn kabuku olorombo lọwọ Manchester United lọjọ Aiku to lọ ninu idije Premier League.

Chelsea niṣẹ to pọ lati ṣe lalẹ lalẹ Ọjọbọ nigba ti wọn ba koju Liverpool ninu idije UEFA Super Cup.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Super Cup

Liverpool lo gba ife ẹyẹ UEFA Champions League ni saa bọọlu to lọ nilẹ Yuropu nigba ti Chelsea gba ife Europa League.

Ọpọ lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu Chelsea lẹyin ti Man U ka ayo mẹrin ọtọọtọ lewọn lọwọ ti wọn ko si le da ọkankan pada.

Koda awọn miiran ni akọnimọọgba tuntun fun ikọ agbabọọlu Chelsea, Frank Lampard ko mọ iṣẹ, wọn ni ki wọn le lọ.

Ṣugbọn Lampard ni awọn ṣetan fun ipenija idije Super Cup pẹlu Liverpool.

Papa isẹre to wa niluu Istanbul lorilẹede Turkey ni ifẹsẹwọnsẹ yoo ti waye.