Ifeanyichukwu Chiejine: Agbábọ́ọ̀lù Chiejine jáde láyé lẹ́yìn ààsàn ráńpẹ́

Ifeanyichukwu Chiejine Image copyright Twitter/NFF
Àkọlé àwòrán Agbabọọlu Super Falcons tẹlẹ jade laye

Iku doro, iku ṣeka, agbabọọlu Super Falcons Naijiria tẹlẹ ri, Ifeanyichukwu Chiejine ti jade laye lẹni ọdun mẹrindinlogoji.

Ajọ to n ri si ere bọọlu ni Naijiria lo kede iku Chiejine loju opo Twitter wọn lọsan Ọjọbọ.

NFF ṣalaye loju opo wọn pe agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri naa ku lẹyin aisan ranpẹ.

Chiejine ṣoju Naijiria nigba mọkanlelọgọta, bẹẹ lo si gba goolu mẹẹdogun sawọn nigba aye rẹ.

Chiejine ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Naijiria akọkọ tọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkandinlogun lọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 2002.

Image copyright Twitter/NFF
Àkọlé àwòrán Iku pa agbabọọlu Super Falcons tẹlẹ

NFF ṣalaye pe Ọjọru ọsẹ yii ni agbabọọlu naa dagbere faye.