Crystal Palace vs Manchester United: Crystal Palace pàkúta sí gaàrí Manchester United ní Old Trafford

Marcus Rashford ati Joel Ward Image copyright Getty Images

Ajẹtun iya ni Manchester United jẹ lọwọ ẹgbẹ agbabọọlu Crystal Palace lọjọ Abamẹta ninu idije Premier League.

Crystal Palace lo kọkọ gba bọọlu sawọn ṣugbọn Manchester United dayo naa pada.

Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ nigba ti Crystal Palace gbayo mii wọ le Man U nigba to ku diẹ ki ere bọọlu naa pari.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Premier League

Tamọtiye! Tammy ta Norwich pa mọ́ lé, bí Chelsea ti gbéra

Lẹyin ọ rẹyin, ẹrin gba ẹkẹ akọnimọọgba Chelsea, Frank Lampard lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea gbegba oroke fun igba akọkọ lati igba to ti gori aleefa gẹgẹ bi akọnimọọgba tuntun ni papa iṣere Stamford Bridge.

Chelsea fẹyin Norwich City gba lẹ nile wọn ni Carrow Road lẹyin ti wọn ti ta ọmi kan ti wọn si jawe olubori ninu omiran ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn ti gba lati igba ti idije Premier League ti bẹrẹ ni saa yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Premier League

Lẹyin iṣẹju mẹta pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun ni Tammy Abraham gba bọọlu sawọn fun Chelsea.

Ṣugbọn Todd Cantwell dayo naa pada lẹyin iṣẹju mẹta mii lo ba di ọmi alayo kọọkan.

Ọjẹwẹwẹ agbabọọlu Chelsea, Mason Mount gbayo wọ le eleyi ti Chelsea fi tun wa niwaju ṣugbọn ẹlẹsẹ ayo Teemu Pukki sọ ere bọọlu ọhun ọmi alayo mejimeji.

Ẹlẹsẹ ayo Tammy Abraham lo gba mii wọ le fun Chelsea eleyi to jẹ ẹlẹẹkeji rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Lampard gbéra sọ!Chelsea run Norwich mọ́ lẹ̀ jégéjégé