Liverpool vs Arsenal: Liverpool kun Arsenal wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bí ẹran àsun 'lójúbọ' Anfield

Mohamed Salah ati David Luiz Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Premier League

Ajura wa lọ, ti ijakandi kọ o! Liverpool kọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lẹkọ ti wọn ko le gbagbe ni papa iṣere Anfield lọjọ Abamẹta.

A na sare ni Liverpool lu Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League nirọlẹ ọjọ Satide.

Ami ayo meji sodo ni wọn fi fẹyin Arsenal gbi lẹ ni Anfield.

Adilemu, Joel Matip lo kọkọ fori kan bọọlu wọ le Arsenal, ki David Luiz to fa Mohamed Salah laṣọ nigba to fẹ gbayo sawọn, ni rẹfiri ba fọn feere pẹnariti.

Salah ko beṣu bẹgba, niṣe lo gba pẹnariti naa wọ le, eleyi to mu Liverpool siwaju pẹlu ami ayo meji sodo.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Premier League

Laipẹ lai jina, Salah tun gbayo sawọn eleyi to jẹ ki Liverpool siwaju pẹlu ami ayo mẹta sodo ti Arsenal ko si ri ọkankan da pada.

Amọ, Lucas Torreira gbiyanju lati dayo kan pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ku iṣẹju marun un ko pari.

Pierre-Emerick Aubameyang ati Nicolas Pepper to ṣẹṣẹ rọpo mọ Arsenal lanfaani lati gba goolu sawọn fun Arsenal, ṣugbọn wọn ko lo anfaani ti wọn ni.