Falconets gbo ewuro soju orilẹ ede Cameroon nínú ìdije eré ti ilẹ Afrika

Ikọ Falconets Image copyright FIFA.com
Àkọlé àwòrán Ikọ Falconets gbo ewuro soju ojugba won ti ile Cameroon

Ẹgbẹ agbaboolu ọjẹ wéwé orilẹ-ede Naijiria ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ ni wọn ti fi agba han ojugbaa wọn ti ilẹ Cameroon.

Awọn agbaboolu yii kogoja lati gba ẹbun wura ti ilẹ Afrika lẹyin ọdun mejila ti wọn ti gba a gbẹyin.

Bo tilẹ jẹ pe, ọmi ni awọn ẹgbẹ agbaboolu naa kọkọ gba ni ori papa Boubker Aamar ni ipele akọkọ ati ikeji ifẹsẹ wọn sẹ naa.

Nigba ti adari eto lori papa pe fun idije ifẹsẹ-wọn- sẹ ojule si ojule ti o mu ki Naijiria gba amin ayo mẹta si meji si ile ojugba wọn.

Ninu eyi ti o ti fun ẹgbẹ agbaboolu ti orilẹ ede yii ni anfaani lati fi ẹyin ojugba wọn gbolẹ

Awọn ẹgbẹ agbabolu mejeeji ni wọn jọ figa gbaga lati jawe olubori ko to di wi pe ẹkọ ko soju mimu fun ikọ ti Cameroon.

Nina ti ikọ ti orilẹ ede Naijiria na ojugba wọn yii fihan wi pe igba akọkọ re lati bii ọdun 2007 lẹyin ẹẹmarun ti wọn ti gbiyanju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDomestic Violence: Ìjà láàrin lọkọlaya sọ aya dèrò ọ̀run