Àgbò Man City tó tàdí mẹ́yìn fi ìkanra na Watford bolẹ̀

Bernardo Silva scored his first Manchester City hat-trick on a desperate day for Watford Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eléyìí ni àsìkò àkọ́kọ́ tí Bernardo Silva yóò gbá góòlù mẹ́ta s'áwọ̀n nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kan látigbà tó ti darapọ̀ mọ́ Manchester City

L'áàrin ìṣẹ́jú méjìdílógún àkọ́kọ́ ni Manchester City gba bọ́ọ̀lù márùn un wọ àwọ̀n Watford tí Watford ò sì le tapútú.

Àfì sí ẹ̀yìn ni Man City fi ìyà tí wọ́n jẹ l'ọ́wọ́ọ Norwich lọ́sẹ̀ tó kọjá nígbà tí wọ́n na Shakhtar Donetsk mọ́lé nínú ìdíje Champions League l'Ọ́jọ́rú.

Nínú ìdíje ọjọ́ Àbámẹ́ta, Bernardo Silva gbá bọ́ọ̀lù mẹ́ta sí àwọ̀n nígbà tí àwọn ọmọ Pep Guardiola fárígá pẹ̀lú gbígbá bọ́ọ̀lù s'áwọ̀n tí wọ́n sì rí góòlù tó pọ̀ jù láti ìgbà tí olùkọ́ni náà ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà ní ọdún 2016.

Ìyà tí 9-0 tí Manchester United ṣe fún Ipswich l'ọ́dún 1995 sì ni ìṣẹ́gun tó ga jù nínú ìtàn ìdíje Premier League, ṣùgbọ́n City jẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù keèje tó na ẹgbẹ́ míràn ní 8-0 ní àsìkò tí a wà yìí.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Báyìí ni Aguero ṣe gbá góòlù keji wọ àwọ̀n Watford.

City gbá bọ́ọ̀ù àkọ́kọ́ sínú àwọn Watford ní àáyá ìṣẹ́jú méjìléláàádọ́ta (52 seconds) sí ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ eré nígbà tí láti ẹ̀sẹ̀ David Silva kí Sergio Aguero ó tó fi kú un. Lẹ́yìn náà ni Riyad Mahrez gbábọ́ọ̀lù sí àwọn Watford.

Bernarndo Silva fi orí gbá góòlù kẹẹ̀rin sí àwọ̀n nígbà tí Nicolas Otamendi gbá ìkaàrún un sínú àwọ̀n. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n padà wá láti ìsimi ìdajì àsìkò, ìkanran Man City dínkù díẹ̀, ṣùgbọ́n Bernarndo Silva gbá bọ́ọ̀lù s'áwọ̀n ní ẹ̀mejì kí Kevin de Bruyne ó tó gbá ẹlẹ́ẹ̀kẹẹ̀jọ s'áwọ̀n.

Related Topics