Newcastle vs Manchester United: Newcastle da iyọ̀ sójú egbò Manchester United

Ole Gunnar Solskjaer Image copyright Getty Images

Aṣe tẹni to de laari, ko si ẹni to mọ tẹni to n bọ. Bayii lọrọ ri nigba ti Wolves kọkọ na Manchester City mọle.

Aṣe orogun wọn, Manchester United ti wọn jọ wa ni ilu kan naa yoo fidi rẹmi bi tawọn naa.

Ẹgbẹ agbabọọlu Newcastle lo ṣina iya fun Man U ni tiwọn ni papa iṣere St. James Park nirọlẹ ọjọ Aiku ninu idije Premier League

Matthew Longstaff lo gbayo naa wọle fun Newcastle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun ku iṣẹju mejidinlogun ko pari.

Image copyright Getty Images

Ọpọ lo ti n sọ pe asiko ti to lati le akọnimọọgba Ole Gunnar Soljskaer lọ lẹyin ti Man U ti n rakoro bi ọmọ ọwọ fun bi igba diẹ bayii.

Guardiola kan ìjàngbọ̀n! Tamọtiye Wolves, Traore ta Man City pa mọ́lé

Iya airo tẹlẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Wolves fi jẹ Manchester City ni papa iṣere Etihad lọjọ Aiku.

Bi awada bi ere ni ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ eleyi ti ọpọ olololufẹ ere bọọlu si lero pe Man City ni yoo jawe olubori.

Image copyright Getty Images

Amọ ọmi odo si odo ni wọn jọ gba ni abala akọkọ ere bọọlu ọhun lẹyin ti awọn mejeeji gbiyanju lati gba goolu sawọn ara wọn.

Eleyi ni igbakeji ti ẹgbẹ agbabọọlu Man City yoo fidi rẹmi ninu idije Premier League ni saa yii lẹyin ti Norwich City ti kọkọ na wọn lai ro tẹlẹ bakan naa.

Adama Traore lo gba goolu mejeeji sawọn fun Wolves

Lampard ń dábírà! Àlùbolẹ̀ ni Chelsea lu Southampton mọ́lé

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti bẹrẹ si ni yọ eruku lala bayii o, alubolẹ ni wọn lu Southampton mọle ninu idije Premier League lọjọ Aiku.

Tamọtiye ti wọn n pe ni Tammy Abraham lo kọkọ ṣide iya lẹyin to gba goolu akọkọ sawọn fun Chelsea nigba ti ere bọọlu ọhun de iṣẹju mẹtadinlogun.

Image copyright Twitter/Premier League

Ọkan lara awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu Chelsea, Mason Mount lo gbayo ẹlẹẹkeji wọle fun Chelsea.

Southanpton ta putu diẹ da ayo kan pada nibi ọgbọn iṣẹju, ṣugbọn Ngolo Kante fọba lee fun Chelsea pẹlu goolu kẹta.

Mitchy Batshuayi lo gba goolu ẹkẹrin wọle fun Chelsea ti ifẹsẹwọnsẹ naa si pari si ami ayo mẹrin sẹyọkan.