Brazil vs Nigeria: Ọ̀mì aláyò kọ̀ọ̀kan lakitiyan Super Eagles pẹ̀lú Brazil jásí

Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ati Brazil Image copyright Getty Images

Ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ to waye laarin ikọ agbabọọlu Naijiria ati Brazil lo pari si ọmi.

Ikọ Supper Eagles Nigeria lo kọkọ sọ bọọlu sinu awọn ilẹ Brazil, nigba ti Joe Aribo to n gba bọọlu fun Glasgow Rangers nilẹ Gẹẹsi ṣo ayo kan wọle, ni igabti idije naa wọ iṣẹju marundinlogoji.

Sugbọn lẹyin ọpọlọ akitiyan ninu abala keji idije ọhun ni ikọ Brazil da bọọlu naa pada si awọn ikọ Naijiria, ni igba ti Casemiro to n gba bọọlu fun ikọ Real Madrid sọ ayo tiẹ wọle.

Ọmi ti wọn ta yii tunmọ si pe, ikọ ilẹ Brazil ti kuna lati bori ninu idije mẹrin ti wọn ti gba sẹyin.

Brazil vs Nigeria: Super Eagles ṣetán láti gbéná wojú Brazil

Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ti ṣetan lati gbena woju ikọ agbabọọlu ilẹ Brazil lọjọ Aiku lorilẹede Singapore.

Ikọ agbabọọlu Brazil ti kọkọ ta ọmi alayo kọọkan pẹlu Senegal l'Ọjọ ọsẹ to lọ nibu ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ.

Ọdun 2003 ni Naijiria ati Brazil jọ koju ara wọn kẹyin ninu ere bọọlu ọlọọrẹsọọrẹ.

Ni papa iṣere orilẹede Naijiria to wa l'Abuja ni Brazil ti lu Super Eagles lalu bolẹ pẹlu ami ayo mẹta sodo.

Akọnimọọgba Supe Eagles Gernot Rohr ti sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti ṣetan lati jẹwọ ara wọn fun Brazil ninu ere bọọlu lorilẹede Singapore.

Bakan naa, minisita fun ere idaraya ati idagbasoke ọrọọdun, Sundare Dare ni awọn agbabọọlu Naijiria fi da oun loju pe didun lọsan yoo so fun Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Brazil.

Minisita ṣalaye pe bo tilẹ jẹ wi pe ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ ni, awọn agbabọọlu Naijiria yoo fi taratara sii.