Patrick Day: Akẹ̀ṣẹ́ kan, Day dèrò ọ̀run lẹ́yìn tó gba ẹ̀ṣẹ́ s'órí

Patrick Day ati Charles Conwell Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Patrick Day: Akẹ̀ṣẹ́ kan, Day dèrò ọ̀run lẹ́yìn tó gba ẹ̀ṣẹ́ s'órí

Iku ogun nii pa akinkanju, iku odo nii pa omuwẹ.

Abẹṣẹ-ku-ojo ọmọ ilẹ Amẹrika kan, Patrick Day ti dero ọrun lẹyin to fi ori ṣeeṣe nigba to ba Charles Conwell ja.

Day to ku ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn dero ile iwosan lọjọ Satide to kọ ja, ko da ko le sọrọ mọ, bẹẹ ni ko mo ohun kankan mọ nitori.

Ipele kẹwaa ija rẹ pẹlu Conwell eyi to waye niluu Chicago lo ti fidi rẹmi lẹyin ti ẹṣẹ ṣakoba fun un lori.

Ọjọ mẹrin ni Day fi wa nile uwosan nibi ti ko ti le gbe apa, gbe ẹsẹ, ko to di pe o wa jẹ Ọlọrun nipe.

Onigbọwọ Day, Lou DiBella lo kede iku rẹ nigba ti o wa pẹlu awọn ẹbi ati ọrẹ rẹ.

DiBella ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe, oloogbe Day ko tiẹ nilo lati ja ẹṣẹ nitori o kawe, bẹẹ lo si ti ile ire jade, ati pe, o ni awọn ohun amuyẹ to le mu ṣe iṣẹ miiran yatọ si ẹṣẹ kikan.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Onigbọwọ Day, Lou DiBella lo kede iku rẹ nigba ti o wa pẹlu awọn ẹbi ati ọrẹ rẹ.

DiBella ni Day pinu lati maa ja ẹṣẹ nitori ẹṣẹ kikan ni iṣẹ to yan laayo, ohun si ni o jẹ nnkan iwuri fun un.

Ẹwẹ, Conwell ti wọn jọ ja naa kẹdun pẹlu ẹbi Day, o ni oun ko gbero iku sii nigba yawọn n ja.

Conwell ṣalaye pe oun gbiyanju lati bori ninu ija naa ṣugbọn oun ko mọ pe iku ni yoo jasi fun alatako oun, Day.

Day jawe olubori ninu ija mẹtadinlogun ninu mejilelogun to kopa ninu rẹ, o fidi rẹmi ninu mẹrin, o si ta ọmi ninu ija kan.

Ọpọ lo n ṣedaro Patrick Day lori ayelujara, wọn kẹdun pẹlu ẹbi rẹ ninu ọrọ ti wọn fi sita.