#U17WC: Mínísítà ní orí ìdúró l'òun ti wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Nàìjíríà àti Hungary tán

Minisita Dare ati awọn Golden Eaglets

Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF

Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun, the Golden Eaglets ya agbado ha si ọpọ lẹnu lẹyin ti wọn gbẹyẹ lọwọ ilẹ Hungary ninu idije ife ẹyẹ agbaye FIFA U-17 World Cup lorilẹede Brazil lalẹ ọjọ Satide.

Koda minisita fun ere idaraya ati ọrọ ọdọ, Sunday Dare sọ pe lori iduro l'oun ti wo ifẹsẹwọnsẹ naa to fi pari nitori ẹru.

Nnkan ko kọkọ ṣẹnu 're fawọn ọjẹwẹwẹ Naijiria lẹyin ti Gyorgy Komaromi gba bọọlu sawọn fun ikọ agbabọọlu Hungary lẹyin iṣẹju mẹta ti ere bọọlu naa bẹrẹ.

Agbabọọlu Samson Tijani dayo naa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun pe ogun iṣẹju.

Amọ, Samuel Major tun fọba lee fun Hungary lẹyin iṣẹju mẹjọ ki Usman Ibrahim to dayo naa pada eleyi to sọ di ọmi alayo mejimeji.

Oluwatimilehin Adeniyi lo fọba lee fun Naijiria nigba ti ere bọọlu ọhun ku iṣẹju mẹjọ ti yoo fi pari.

Balogun Golden Eaglets, Tijani lo gba goolu ẹlẹẹkẹrin sawọn Hungary eleyi to jẹ ki Naijiria gbegba oroke pẹlu ami ayo mẹrin si meji.

Ẹwẹ, minisita ere idaraya ni o da oun loju pe ikọ agbabọọlu Naijiria yoo tubọ fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn toku.

Minisita ṣalaye oun mọ pe awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu Naijiria yoo fakọyọ ninu idije FIFA U-17 World nitori oun wo wọn nigba ti wọn n gbaradi niluu Abuja.