Chelsea vs Manchester United: Àwọn agbábọ́ọ̀lù Ole lé Chelsea kúrò ní ìdíje Carabao Cup

Agbabọọlu Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ agbabọọboolu Manchester United ya ọpọ lẹnu lẹyin ti wọn fiya jẹ Chelsea mọle ninu idije Carabao Cup.

Mracus Rashford lo kọkọ gbayo wọle lẹyin iṣẹju mẹẹdọgbọn ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun.

Mchy Batshuayi dayo naa pada lai fọta pe.

Amọ Rashford tun fọba lee fun Manchester United lẹyin to gbayo keji ti wọn fi jawe olubori wọle fun Man U.

Àwọn ọmọ ológo Liverpool lé kúrò ní ìdíje Carabao Cup

Yoruba bọ, wọn ni aileja lojude ile baba me ko de bi. Bayii ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ṣe ya ọpọ ololufẹ ere bọọlu lẹnu lẹyin ti wọn fiya jẹ Liverpool mọle.

Shkodran Mustafi lo kọkọ sẹesi gbayo sawọn Arsenal lẹyin iṣẹju mẹfa ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun.

Amọ, Lucas Torreira dayo naa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di iṣẹju mókandinlogun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹlẹsẹ ayo, Gabriel Martinelli gba goolu meji sawọn fun Arsenal laarin iṣẹji mẹwaa, ni ere bọọlu ba di ami mẹti sẹyọkan.

James Milner lo gbayo keji wọle fun Liverpool ki agbabọọlu Arsenal tẹlẹ Alex Oxlade Chamberlain ati Divock Origi to gbayo ẹlẹkẹta ati ẹlẹẹkẹrin sile Arsenal.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣugbọn Arsenal lo pada jawe olubori nigbẹyin gbẹyin lẹyin ti Joseph Willock gba goolu karun un wọle fun Arsenal.

Ọjọ́ ẹ̀san dé! Chelsea ṣetán láti gb'ẹ̀san 4-0 lára Manchester United

Ọjọ n bọ ni Oluwa wi, ṣugbọn ọjọ ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Manchester United yoo tun jọ ta kan-ungbọn ti de lalẹ Ọjọru.

Ami ayo mẹrin sodo ni Manchester United fi ṣagba Chelsea nigba ti wọn kọkọ jọ waako ni ibẹrẹ saa bọọlu yii.

Eyi ni igbakeji ti ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji yoo koju ara wọn lati igba ti saa yii ti bẹrẹ.

Ni papa iṣere Stamford Bridge ni ifẹsẹwọnsẹ toni yoo ti waye ninu idije ife Carabao Cup.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọdun 2012 lawọn mejeeji jọ pade kẹyin ninu idije yii, Chelsea lo jawe olubori pẹlu ami ayo marun un si mẹrin nigba ti ere bọọlu naa di womi ki n gba siọ.

Chelsea n yeruku lala bayii, koda wọn jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ meje ti wọn kopa ninu rẹ kẹyin.

Ipo kẹrin ni Chelsea wa lori tabili idije Premier League, nigba ti Man U wa ni ipo keje.

Igba mẹrinlelọgọsan an ni Chelsea ati Manchester United ti jọ koju ara wọn, igba kẹfa si ree tawọn mejeeji yoo koju ara wọn ninu idije EFL.

Chelsea jawe olubori lẹẹmẹwaa ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkanla ti wọn kẹyin ninu idije EFL.

Manchester United ni ti wọn jawe olubori ninu mẹfa ninu ifẹsẹwọnsẹ meje ninu idije EFL ti wọn gba pẹlu awọn ẹgbẹ agbabọọlu to n kopa ninu idije Premier League.