Jose Mourinho: Ayélujára ń hó yaya lórí ọ̀rọ̀ Mourinho pẹ̀lú Arsenal

Unai Emery ati Jose Mourinho

Oríṣun àwòrán, Twitter/Express Sport

Yoruba bọ wọn ni bi ohun ti a n ba n jẹ ba tan, ohun ti a kii jẹ naa lo ku. Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ilẹ Gẹẹsi lo n sọ pe akọnimọọgba Chelsea ati Manchester United nifẹ si ko gba iṣẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.

Ọrọ yii lọpọ eeyan n gba bi ẹni n gba igba ọti lori ayelujara opo Twitter papaajulọ lati igba ti Arsenal ti ri iya he lọwọ Liverpool ninu idije Carabao Cup ni papa iṣere Anfield lalẹ Ọjọru.

Iroyin sọ pe Mourinho n wa iṣẹ si ilẹ Gẹeṣi nitori nibẹ lo ti ṣaṣeyọri nibi to gba ife ẹyẹ idije Premier League nigba mẹta ọtọtọtọ.

Ilẹ iroyin ESPN tiẹ sọ pe Mourinho ṣetan lati ṣe akọnimọọgba ikọ Arsenal ti wọn ti fọwọ osi juwe ile fun Unai Emery.

Eleyi jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ ololufẹ ere bọọlu papaajulọ idije Premier League nitori Mourinho sọrọ alufansa si Arsenal fun ọpọlọpọ ọdun.

Mourinho ti kọ lati gba iṣẹ akọnimọọgba ni ẹgbẹ agbabọọlu Benfica ati ikọ agbabọọlu kan lorilẹede China.

Bakan naa laagbọ pe o ṣeeṣe ki Mourinho pada si ikọ Real Madrid eleyi to ti tukọ rẹ ri tẹlẹ.