Watford vs Chelsea: Chelsea sọjí lu Watford mọ́lé lẹ́yìn tí Man U fìyà jẹ wọ́n

Tammy Abraham ati Christian Pilisic Image copyright Getty Images

Ooṣa ma jẹki ẹni to gọ o gbọn, ka le maa ri i tujẹ bi iṣu. Bayii lọrọrọ ri pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nigba ti wọn koju Watford nile wọn.

Ẹ o ranti pe Manchester United lu Chelsea mọle laarin osẹ ninu idije Carabao Cup eleyi to mu Chelsea dero ile lati idije naa.

Amọ Watford lo fori kan iya ti Chelsea jẹ lọwọ Man U, ami ayo meji sẹyọkan ni Chelsea fi gbo ewuro soju Watford nile wọn.

Tamọtiye Tammy Abraham lo gbayo akọkọ sawọn Watford lẹyin iṣẹju marun un pere ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Agbabọọlu ilẹ Amẹrika, Christian Pulisic lo gba goolu keji wọle fun Chelsea.

Amọ, Gerard Deulofeu dayo kan pada nigba to gba pẹnariti wọle Watford nigba ti ere bọọlu ku iṣẹju mẹwaa ti yoo fi pari.

Dákúdájí Manchester United tún ṣubú yakata nílé Bournemouth

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti di dakudaji bi ọkọ ẹ tii ẹ rọmi bayii, lẹyin ti Bournemouth fiya jẹ wọn lairotẹlẹ lọjọ Satide.

Lẹyin ti wọn lu Chelsea pẹlu ami kan sodo laarin osẹ ninu idije Carabao Cup, ọpọ lo ti ro pe Man U yoo fakọyọ nigba ti wọn ba koju Bournemouth.

Image copyright Getty Images

Amọ, ami ayo kan sodo ni Bournemouth fi ṣagba wọn, Joshua King lo gbayo naa wọle nigba to ku diẹ ki ipele akọkọ ko pari.

Man U gbiyanju agbara wọn, amọ pabo ni gbogbo igbiyanju wọn jasi.