Raheem Sterling: Guardiola ní kí Madrid mú £70m pẹ̀lú Hazard wá fún Sterling

Raheem Sterling, Eden Hazard ati Gareth Bale Image copyright Getty Images

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ilẹ Yuropu lo sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ṣetan lati fi aadọrin miliọnu owo pọn-un(£70 million) ra Raheem Sterling lati Manchester City.

Koda, Madrid tun ṣetan lati fi agbabọọlu Gareth Bale le owo naa.

Igbin tẹnu mọ'gi ni Madrid fi ọrọ Sterling ṣe, lẹyin ti wọn ti n sọọ lati ibẹrẹ saa bọọlu yii.

Akọnimọọgba Man City ti da wọn lohun lẹyin to sọ pe ki Madrid fi Eden Hazard le aadọrin miliọnu owo pọn-un(£70 million) ti wọn ba fẹ ra Sterling ni tootọọ.

Ẹwẹ, agbabọọlu Bale fun ra rẹ ti n wa ọna lati kuro ni Real Madrid papaajulọ lati igba ti akọnimọọgba Zinedine Zidane ti pada si ikọ agbabọọlu naa.

Ohun ti ẹnikẹni ko mọ bayii ni bo ya Pep Guardiola nifẹ si ki Bale darapọ mọ Man City tabi ki Sterling fi ikọ agbabọọlu naa silẹ lọ si Real Madrid.

Iroyin sọ pe Madrid yoo ran awọn aṣoju lati lọ wo Sterling nigba ti England ba koju Montenegro ati Kosovo ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede for idije EURO loṣu to n bọ.

Bakan naa lawọn aṣoju Sterling ṣepade pẹlu eekan ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid, Jose Angel Sanchez ki saa bọọlu yii to bẹrẹ.

Ṣugbọn ohun ti a gbọ nipe Man City ko ṣetan lati jọwọ Sterling bayii, lẹyin to wa lara awọn agbabọọlu to fakọyọ julọ fun ẹgbẹ agbabọọlu naa.