Liverpool vs Manchester City: Gbé bọ́dì ẹ! Ajá Liverpool gbéra pakuru mọ́ Manchester City.

Awọn agbabọọlu Liverpool ati Manchester City Image copyright Getty Images

Liverpool ti fi sọ àmì ayò tí wọ́n fi jù Manchester City lọ nínú ìdíje EPL di mẹ́sàn lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n dá aṣọ ìyàn fún City.

Fabínho ló fi bọ́ọ̀lù olóyì sẹ City lọ́wọ́ lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́fà [(6) sí ìgbà tí wan bẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀.

Ìṣẹ́jú mẹ́tàlá (13) sí ìgbà tí eré bẹ̀rẹ̀ ni Mohamed Salah fi orí gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n City.

Image copyright PA Media
Àkọlé àwòrán Fabinho ló kọ́kọ́ gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n City

Liverpool ò dékun àti fi ìyà jẹ Manchester City títí di ìṣẹ́jú mọ́kànléláàádọ́ta (51) nígbà tí Sadio Mane gbá bọ́ọ̀lù kẹẹ̀ta sí àwọ̀n Manchester City.

Pep Guardiola yọ atamátàsẹ́ Man City, Sergio Aguero jáde nígbà tí eré di àádọ́rin (70) ìṣẹ́jú tó sì fi Gabriel Jesus rọ́pò rẹ̀.

Image copyright Laurence Griffiths
Àkọlé àwòrán Sadio Mané ló gbá góòlù keèta sí àwọ̀n Man City

Man City ráyè dá góòlù kan padà nìgbà tí Bernado Silva gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n Liverpool ní ìṣẹ́jú keèjìdílọ́gọ́rin (78).