Níbo lórí n gbé Zlatan Ibrahimovic lọ nínú ìrìnàjò eré bọ́ọ̀lù

Aworan Zlatan Image copyright Ibra_official
Àkọlé àwòrán Níbo lórí n gbé Zlatan Ibrahimovic lọ nínú ìrìnàjò eré bọ́ọ̀lù

Lẹyin nnkan bi ọdun kan le diẹ to darapọmọ ẹgbẹ agbabọọlu LA Galaxy, agbabọọlu ọmọ orile-ede Sweden nii, Zlatan Ibrahimovic ti dagbere o digba fun ẹgbẹ naa.

Loju opo Twitter rẹ ni Zlatan fi ikede idagbere fawọn alatilẹyin ẹgbẹ naa si lọjọru.

Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, Zlatan ni oju oun ti ri to ti oun si bori gbogbo ipenija to koju oun.

O dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ Galaxy to si ni itan igbe aye oun ṣi n tẹsiwaju.

Lẹnu ọjọ mẹta yi ni ọrọ n ja rainrain boya yoo buwọ lu iwe fẹgbẹ naa tabi yoo lọ amọ bayi, o jọ pe Zlatan tun ti n wa ẹgbẹ mi ti yoo ti darra lori papa.

Ki lawọn eeyan n sọ nipa rẹ?

Ko ti daju ibi ti Zlatan yoo lọ bayi ṣugbọn o ti n ta awọn eeyan lolobo pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu kan ti n fifẹ han si pe ki oun darapọ mọ wọn.

Ikede rẹ yi ti mu ki iriwisi ọtọọtọ wa .

Inu awọn kan dun si ,wọn si ti ni ki o tete ma pada bọ wa si Manchester United to fi silẹ

Awọn miran ni tohun ti bi awọn ko ti ṣe fẹran rẹ, ipa to ko ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin

Image copyright Ibra_official
Àkọlé àwòrán Zlatan: Èyí mo ṣé tó, àsìkò tó láti tèsíwájú nínú ìrìnàjò mi

Ibeere tawọn kan n bere ni pe ki gan an lo gbe ṣe nigba to wa ni LAGalaxy tariwo rẹ si wa pọ to bayii

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

Goolu mẹtalelaadọta ni Zlatan Ibrahimovic jẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrindinlọgọta to ti kopa nigba to wa ni LA Galaxy.

Ṣaaju ko to darapọmọ Galaxy lo ti gba fun Manchester United, PSG, Barcelona,Inter Milan ati Ajax.

Ẹni ọdun mejidinlogoji nii ṣe.