Etuhu: Ilé ẹjọ́ ni agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà, Dickson Etuhu jẹ́bi ẹ̀sùn títa ìdíje

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Etuhu: Ilé ẹjọ́ ni agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà, Dickson Etuhu jẹ́bi ẹ̀sùn títa ìdíje

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu bii Manchester City, Sunderland, Preston, Blackburn ati Fulham ni agbabọọlu ọmọ Naijiria, Dickson Etuhu.

Dickson Etuhu ni awọn kan ti kọkọ ro pe o ti bọ lọwọ ifiyajẹni tẹlẹ ki igbẹjọ naa to tun jade.

Ile ẹjọ kotẹmilọrin Stockholm sọ pe Etuhu ati agbabọọlu miran ti wọn ko darukọ ẹ jọ gbiyanju lati jẹ ki adilemu AIK Kyriakos, Kenny Stamatopoulos.

Wọn ni awọn mejeeji ni ki Kenny ta idije ẹgbẹ agbabọọlu wọn fun ti Sweden.

Idije laarin ẹgbẹ agbabọọlu Etuhu ati Sweden ninu idije oni ipele akọkọ ẹgbẹ si ẹgbẹ lọdun 2017.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

Dickson jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogoji agbabọọlu agba to ti fi ẹgbẹ AlK Solna silẹ naa ni oun yoo tun ẹjọ naa gbe lọ sile ẹjọ to ga julọ.

Ile ẹjọ naa ni awọn ẹri to kun to ṣafihan ohun ti awọn agbabọọlu mejeeji fun Stamatopoulos fihan pe wọn jẹbi ẹsun naa.

Ile ẹjọ naa ni ẹṣẹ nla ni agbabọọlu Dickson yii ṣe si orilẹ-ede wọn.

Igba ogun ni Etuhu ti gba bọọlu fun orilẹ-ede Naijiria labẹ Super Eagles, yatọ si ti ẹgbẹ ninu idije 2008 ati 2010 pẹlu ti idije agbaye ni South Africa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAeroplane House: Látọdún 1999 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí fún ìyàwó mi ọ̀wọ́n