Kí láwọn ohùn àmúyẹ tí kọmẹńtátọ̀ tó dáńtọ́ gbọ́dọ̀ ní?

Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Aworan Ernest Okonkwo ati awọn kọmẹntátọ̀ miran nibi ti wọn ti n pitu

Lara akoko ti awọn ọmọ Naijiria maa n ṣafihan idunnu ni igba ti ikọ agbabọọlu Naijiria ba n jade sori papa ere bọọlu.

Ninu ohun to maa n ṣe koriya fun wọn lasiko yi ni bi awọn agbabọọlu ti ṣe maa n tasẹ ati bi ẹni to n ṣalaye bi nnkan ṣe n lọ lori papa naa ba ṣe n pitu tiẹ naa.

Latari eleyi,o jẹ ohun iyalẹnu fawọn ololufẹ ere boolu nigba ti afihan ati ọrọ alaye ta mọ si 'commentary' lede oyinbo ko lọ geere nigba ti Super Eagles Naijiria koju akẹ́gbẹ wọn lati Benin Republic.

Rudurudu ati ailọ-deede eto naa lo n bi ibeere pe ṣe ileeṣẹ amohunmaworan Naijiria ko tilẹ ṣe igbaradi kankan ki wọn to bẹrẹ afihan ifẹsẹwọnsẹ naa ni?.

Bakan naa lo mu iwoye wa ti a si fi ni ka beere pe ki lawọn ohun to yẹ ki kọmẹntatọ ni lamuye ki o to le e bọ si ori afẹfẹ pe ohun fẹ ṣalaye ifẹsọwọnsẹ to n lọ.

Ki a ba le gbọ ọrọ yii ye daadaa ni ki a mu awọn gbajugbaja kọmẹntatọ ni Naijiria to dantọ ki a baa le mọ ohun ti wọn ṣe taraye fi gba wọn lọga nidi iṣẹ kọmẹntari.

Ernest Okonkwo

Bi wọn ba n porukọ akọni ninu awọn kọmẹntatọ ere bọọlu,yoo ṣoro ki a ma fi ida Ernest Okonkwo lalẹ gaara.

Ọdun mọkandinlọgbọn ti o faye silẹ, niṣe ni awọn ọmọ Naijiria n ṣele de pẹlu itu to maa n pa pẹlu apejuwe to munadoko nipa ohun to n ṣẹlẹ lori papa.

Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Kí láwọn ohùn àmúyẹ tí kọmẹńtátọ̀ tó dáńtọ́ gbọ́dọ̀ ní

Awọn to mọ ọ nigba aye rẹ kan sara sii ti wọn si fun un ni orisirisi inagije to jọ mọ bi o ti ṣe maa n hun ọrọ lalai dena pẹnu.

Lara awọn inagijẹ yi la ti ri ''Intercontinental Ballistic Missile Commentator,.

Image copyright Facebook/Yinka Craig
Àkọlé àwòrán Yinka Craig naa jẹ ogbontarigi kọmẹntátọ̀ ni Naijiria nigba aye rẹ

Okonkwọ gẹgẹ bi ohun ti agbaọjẹ ere bọọlu ni Segun Odegbami ti ṣe sọ, a maa fun awọn agbabọọlu lorukọ ti eyi a si maa mu inu awọn to n fọkan ba ere naa lọ lori rẹdio dun.

''Dean of Defence'' ''Mathematical Odegbami'' ''Chairman Chrsitian Chukwu'' ati ''Elastic Elahor'' wa lara awọn orukọ to fi n ṣapejuwe awọn agbabọọlu lori papa.

Image copyright Google

Ṣẹ ẹ ranti apejuwe ''Nigeria score Nigeria!'' to ṣe nigba ti Godwin Odiye fori gbe bọọlu wọnu awọn Naijiria lọdun 1977.

Ti a ba n sọrọ ki eeyan dantọ, ọga ni Okonkwo ninu ṣiṣe alaye ohun to n lọ lori papa ere bọọlu

Awọn kọmẹntatọ miran ninu itan Naijria ti wọn pegede ti wọn fi gbọrọ jẹka ni

  • Isola Folorunsho
  • Kelvin Ejiofor
  • Yinka Craig
  • Sabastine Ofurum
  • Emeka Odikpo
  • Fabio Lanipekun
  • Walter Oyatogun

Àìsàn ìtọ̀ súgà kò túmọ̀ sí pé èèyàn ti gba ọjọ́ ikú- Dókítà Wilson

Góòlù pọ̀ ní ìlú Madaka ṣùgbọ́n wọn kò ní ọ̀nà fún ọgọ́rùn ún ọdún

Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu NTA lórí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìdíje bọ́ọ̀lù

Ilé ẹjọ́ ni agbábọ́ọ̀lù ọmọ Nàìjíríà, Dickson Etuhu jẹ́bi ẹ̀sùn títa ìdíje Sweden