Lionel Messi: Thiago Silva ìwà agọ̀ ló mú Messi sọ fun akọ́nimọ̀ọ́gbá Brazil pé kó gbẹ́nu dákẹ́

Lionel Messi ati Willian Image copyright Other

Bo tilẹ jẹ pe Messi naa lo gba goolu kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Argentina fi bori sawọn.

Ki lo le mu ki agbabọọlu sọ fun akọnimọọgba pe ẹnu rẹ n run?

Gbajugbaja agbabọọlu Barcelona to jẹ ọmọ Argentina lo sọ fun akọnimọọgba Brazil, Tite pe ko yee sọrọ mọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹẹsọrẹẹ to waye laarin orilẹ-ede mejeeji lorilẹ-ede Saudi Arabia lọjọ Ẹti.

Messi ati Tite tahun si ara wọn nigba ti ere bọọlu naa si n gbona girigiri, bo tilẹ jẹ pe Messi naa lo gba goolu kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Argentina fi bori sawọn.

Messi kan ṣadeede lọ sẹgbẹ kan lori papa nibi ti Tite wa, nibẹ lo ti fi ika sẹnu to si ni ''fẹẹmu'' fun akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Brazil.

Tite fun ra rẹ ṣalaye pe lootọọ loun ti n ṣaroye fun rẹfiiri pe nipa bi ifẹsẹwọnsẹ ṣe n lọ, ati pe oun ati Messi jọ ni gbolohun asọ nigba ti ipele akọkọ ere bọọlu pari.

Akọnimọọgba Brazil ni o yẹ ki Messi gba kaadi ikilọ yẹlo, lẹyin naa lọ sọ pe ki oun gbẹnu dakẹ, bayii loun sọ fun un pe ko dakẹ ẹnu rẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, balogun ẹgbẹ agbabọọlu Brazil, Thiago Silva bu ẹnu ẹtẹ lu ihuwasi Messi si Tite.

O ni iwa ti ko boju mu ni lati sọ pe ki agbalagba gbẹnu dakẹ.

Silva fikun ọrọ rẹ pe alaṣeju ni Messi, oun nikan lo fẹ fọn feere, o fẹ dari ere bọọlu naa, bakan naa lo n ṣe ariyanjiyan pẹlu rẹfiri.