Lesotho vs Nigeria: Nàìjíríà lu Lesotho lu lálùbolẹ̀ mọ́lé wọn

Victor Osimhen atawọn akẹgbẹ rẹ Image copyright Twitter/Super Eagles

Alubolẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Naijira, Super Eagles lu Lesotho mọle wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ere bọọlu ilẹ Afirika, 2021 AFCON qualifiers.

Lesotho kọkọ ta biọbiọ lẹyin ti Masoabi Nkoto gbayo sawọn Naijiria lẹyin mọkanla ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Ṣugbọn a ju ara wa lọ bi ti ijankadi kọ o, Alex Iwobi lo dayo naa pada lẹyin iṣẹju mẹẹdogun tawọn Lesotho gbayo wọle Naijiria.

Ko pẹ ko jina ni elege ara, Samuel Chukwueze fọba lee fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles.

Ẹlẹsẹ ayo, Victor Osimhen eleyi tawọn Lesotho bẹru ki ifẹsẹwọnsẹ naa to bẹrẹ lo gba goolu ẹlẹẹkẹta wọle.

Osimhen tun ṣe bẹẹ gbayo ẹkẹrim wọle ni Naijiria ba jawe olubori pẹlu ami ayo mẹrin si meji.

'Osimhen àti Aribo ni Lesotho bẹ̀rù jù nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà'

Bi ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ti ṣetan lati koju Lesotho, akọnimọọgba Lesotho, Thabo Senong ti sọ pe ẹlẹsẹ ayo, Victor Osimhen ati Joe Aribo lawọn bẹru ju.

Ẹgbẹ agbabọọlu Lesotho ti wọn n pe ni Crocodiles ta ọmi 1-1 pẹlu Sierra Leone l'Ọjọru ninu ifẹsẹwọnsẹ lati pegede fun idije 2021 AFCON.

Akọnimọọgba Senong ni Lesotho ko gbọdọ fun Osihmen ati Aribo laye, ti wọn ba fẹ bori Naijiria.

Image copyright Twitter/Joe Aribo

Senong ṣalaye pe ''Super Eagles ni awọn agbabọọlu to dantọ to to gbangba sun lọyẹ, amọ Lesotho le fagba han Naijiria ti wọn ba mura gidigidi.''

Akọnimọọgba Lesotho ni Osihmen ati Aribo ti fakọyọ fẹgbẹ agbabọọlu wọn loke okun, idi niyii ti fi gbọdọ mu wọn daadaa.

Naijriria lo wa loke tente ni isọri ''L'' lẹyin ti wọn pokọ iya fun Benin pẹlu ami ayo meji sodo l'Ọjọbọ niluu Uyo.

Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria lo gba ipo kẹta ninu idije 2019 AFCON ti waye lorilẹede Egypt.