Ballon D'or 2019: Ronaldo ló dáńtọ́ jùlọ (GOAT), bó tilẹ̀ jẹ́ pé Messi ló gb'àmì ẹ̀yẹ Ballon D'or

Cristiano Ronaldo ati Lionel Messi Image copyright Instagram/cristiano

Lootọọ ni aramọnda agbabọọlu Lionel Messi gba ami ẹyẹ Ballon D'or fun igba kẹfa bayii, ṣugbọn aṣoju orogun rẹ, Jorge Mendes faake kọri.

O ni Cristiano Ronaldo lagbabọọlu to dantọ julọ laye ninu itan.

Ronaldo kọ lati lọ si ibi ayẹyẹ naa to waye lalẹ ọjọ Aje niluu Paris lorilẹ-ede Faranse, koda oun lo gba ipo kẹta nigba ti adẹyinmu ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Virgil van Dijk ṣe ipo keji mọ Ronaldo lọwọ.

Ko si agbabọọlu to tii gba ami ẹyẹ naa to Messi, ẹni to ti gba a fun igba kẹfa bayii, lati igba ti wọn ti bẹrẹ fifi ami ẹyẹ naa dawọn agbabọọlu to fakọyọ julọ lọla.

Ronaldo lo tun tẹle Messi lẹyin t'oun naa ti gba ami ẹyẹ Ballon D'or fun igba marun un ọtọọtọ.

Nibo ni Ronaldo wa nigba ti ayẹyẹ Ballon D'or n lọ lọwọ niluu Paris?

Ilu Milan lorilẹ-ede Italy lo wa nibi ti wọn ti fami ẹyẹ agbabọọlu to dara julọ ni idije liigi Serie A fun saa 2018-2019 daa lọla.

Eyi ni igba akọkọ ti Messi yoo gba ami ẹyẹ Ballon D'or lati ọdun 2015, Ronaldo lo gbami ami ẹyẹ naa lọdun 2016 ati 2017, nigba ti Luka Modric Real Madrid gba a lọdun 2018.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA

Ọpọ lo gbagbọ pe Messi ni ami ẹyẹ t'ọdun yii tọ si lẹyin to gba goolu mọkanlelaadọta ninu ifẹsẹwọnsẹ aadọta to gba ni saa bọọlu 2018-19.

Àkọlé àwòrán Ballon D'or 2019: Ronaldo ló dáńtọ́ jùlọ (GOAT), bó tilẹ̀ jẹ́ pé Messi ló gb'àmì ẹ̀yẹ Ballon D'or

Ija ilara ko le tan laelae, ajuwọn lọ ko ṣee wi lẹjọ, Virgil van Dijk to ṣe ipo keji ni Messi ni Eleduwa gbade ere bọọlu fun un.

Van Dijk ni o yẹ kawọn tubọ maa gbaṣoba rabandẹ fun anjannu agbabọọlu ti wọn n pe ni Messi.