Manchester United vs Tottenham: Man United ré Mourinho àti Tottenham lẹ́pa lórí pápá Old Trafford

Mourinho ati awọn agbaabọọlu Man U ati Tottenham Image copyright Getty Images

Papa iṣere Old Trafford yeruku lala lẹyin ti Tottenham ati manchester United tutọ sira wọn loju ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League to waye lalẹ Ọjọru.

Manchester United rii wi pe ipadabọ wa Jose Mourinho si papa iṣere Old Trafford, iya lo ba de.

Lẹyin iṣẹju mẹfa ti ere bọọlu ọhun bẹrẹ ni Marcus Rashford gbayo alakọkọ sawọn fun Manchester United eleyi to mu Man U wa niwaju.

Man U gbiyanju lati gbayo keji wọle, amọ Deli Alli sọ ere bọọlu ọhun di ọmi alayo kọkọkan.

Ẹlẹsẹ ayo Rashford tun fakọyọ kete ti wọn bẹrẹ ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa lẹyin to gba pẹnariti wọle Tottenham eleyi to mu ki Man U pada maa siwaju.

Ológìnní t'àjò dé...Mourinho padà sí Manchester United lónìí!

Oni lonii jẹ ẹni a bẹ lọwẹ. Lalẹ Ọjọru ni gbajugbaja akọnimọọgba Jose Mourinho yoo pada si papa iṣere ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United nibi to ti ṣiṣẹ ki wọn to fọwọ oṣi juwe ile fun un lọdun 2018.

Amọ ikọ agbabọọlu Tottenham ni Mourinho n ko o lọ koju Man United lọtẹ yii lẹyin to gbaṣẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa ni kopẹ kopẹ yii.

Image copyright Getty Images

Ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ti jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba ninu idije Premier League lati igba ti Mourinho ti rọ pe Mauricio Pochettino gẹgẹ bi akọnimọọgba Spurs.

Koda ipo Tottenham ti gberu si lori tabili idije Premier League, ipo kẹfa ni wọn wa bayii lẹyin ti wọn fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba sẹyin.

Awọn agbabọọlu Tottenham gan an ti mọ pe igba ọtun ti de, agbabọọlu bi Dele Alli ti ina ere bọọlu rẹ ti n jo ajo rẹyin tẹlẹ ti sọji bayii.

Ipo kẹfa ni Man U wa ki wọn to da Mourinho duro lẹnu iṣẹ, ṣugbọn ipo kẹwaa ni wọn wa bayii labẹ aṣẹ akọnimọọgba tuntun, Ole Gunnar Solskjaer.

Ọmi alayo meji meji ni Manchester United ta pẹlu Aston Villa ninu ere bọọlu ti wọn gba kẹyin lọjọ Aiku.